ÈDÈ
ÈDÈ
Èdè lawo,
Awo lèdè.
Àìgbédèe ègà,
Lafi ñ pè wón ní pàátó.
Eni bá gbóhùn eye,
Á mò péye ñ wí nnkan.
Akéwì tí ò gbédè ,
E jé á korí è sígbó;
Nítorí itó lásán ló ñ já kiri.
Akígbe tí ò mèdè,
E jé á gbe fóòsà mì;
Nítorí ariwo ló ñ paáká.
Bá a bá fé tù fún òrò,
Àni bópìtàn óò bá pítan,
Básòtàn yóò bá sòtàn,
Tárótan ró ti è náà ti è tán
Ní kíkún,
Èdè un lomi àbùwè,
Èdè un lomi àbùmu.
Lìngúísííkì o kú ìkàlè,
Litirésò o kú ìjòkóó.
Béye bá fapá kan fò,
Jíjá ní í ñ ja.
Láàngbàsà dé,
Òkun lolorí omi.
Láti inú ìwé láàngbàsà odún 1984 lábé àkosílè Olóògbé Òjògbón Afolábí Olábímtán
Èdè lawo,
Awo lèdè.
Àìgbédèe ègà,
Lafi ñ pè wón ní pàátó.
Eni bá gbóhùn eye,
Á mò péye ñ wí nnkan.
Akéwì tí ò gbédè ,
E jé á korí è sígbó;
Nítorí itó lásán ló ñ já kiri.
Akígbe tí ò mèdè,
E jé á gbe fóòsà mì;
Nítorí ariwo ló ñ paáká.
Bá a bá fé tù fún òrò,
Àni bópìtàn óò bá pítan,
Básòtàn yóò bá sòtàn,
Tárótan ró ti è náà ti è tán
Ní kíkún,
Èdè un lomi àbùwè,
Èdè un lomi àbùmu.
Lìngúísííkì o kú ìkàlè,
Litirésò o kú ìjòkóó.
Béye bá fapá kan fò,
Jíjá ní í ñ ja.
Láàngbàsà dé,
Òkun lolorí omi.
Láti inú ìwé láàngbàsà odún 1984 lábé àkosílè Olóògbé Òjògbón Afolábí Olábímtán



Comments
Post a Comment