Tragic

Ó LÁGBÁRA😭

Iná á jó lóko 
Á pará ilé
Àjà á jìn níyẹ̀wù 
Á pèèrò ọ̀nà
Emọ́ á kú 
Ojú òpó á dí
Àfìrìmàjò á kú, 
Ẹnu isà rẹ̀ á sọ̀fọ̀.
Erin lọ nígbó 
Tigbótijù pa lọ́lọ́
Efọ̀n lọ lọ́dàn
Ọ̀dàn ń mì tìtì

Mo dúró, ojú mi ò tókè
Mo bẹ̀rẹ̀, ojú mi ò tólẹ̀
Ajá kú pẹlú gbígbó
Àgùntàn kú pẹ̀lú bọ̀lọ̀bọ̀lọ̀ lọ́rùn.
Ọmọ ọlọ ò leè lọ ìyá rẹ̀ mọ̀
Ọmọ odó ò leè gún ìyá rẹ̀ mọ́
Ojú kọ̀ kò là.
Etí kọ̀ kò gbọ́
Etí ò sí mọ́ 
Orí dàpólà igi
Àtàǹpàkò ò sí mọ́
Ọwọ́ dìlagbà

Pàkúté ò leè jẹran mọ́
Ọṣán já ọrún dọ̀pá
N̄ǹkán se
Awọ́ ti ya, gọ̀ǹgọ̀ ò wúlò mọ̀
Onílù wá ń wòran awo
Jagunlabí tí ń peni
Ò leè peni mọ́
A pè é kò dáhùn.
Àfi kédùà ó kó wa yọ 
Àfi kọ́ba òkè ó gbà wá nínú ọ̀ràn yí
Káwa táa rọ́jọ́ òní
Kálejọ ṣẹ̀míì.

Láti ọwọ́ Saintpradol✍🏾

Comments

Post a Comment

Popular Posts