ÀBẸ̀NI👸🏻💐
Orí kìíní
Mo rí òdòdó💐
Kìí kúkú ṣe pé n̄ kò rí obìnrin rí, ṣùgbọ́n ọjọ́ àkókò tí mo rí awẹ́lẹ́wà, ọ̀pẹ́lẹ́ńgẹ́, ọmọbìnrin yìí, ohun tí ó so lọ́kàn mi yàtọ̀ sí èyí tí mo ti ní ìmọ̀lára rẹ̀ rí. Ṣe bí mo jókòó ni bí mo ti wọ gbọ̀ngán ìdánilékòó pẹ̀lú ọ̀rẹ́ mi agùntáṣọọ́lò Sàámú ọmọ Ògbó. Ní ọwọ àárín ni mo jókòó sí láti lè mọ ohun tó ń lọ níwá lẹ́yìn.
Kò pẹ́ ni adarí ìdánilékòó dọ́wẹ̀ẹ́kẹ̀ pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́. Ẹ̀rín tí àwọn akẹgbẹ́ mi rín ni mo fi ṣàkíyèsí ọmọbìnrin aláwọ̀ wúrà tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ mi. Bi òun náà ti rẹ́rìn-ín, pẹ́kí ni ojú mi ṣe rẹ́kí eyín funfun ẹnu rẹ̀. Mo bi í léèrè ohun tí olùkọ́ sọ tí gbogbo wọ́n fi rẹ́rìn-ín pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ lójú mi. Ó sì fèsì láìwojú mi. Iyè mi kò tilẹ̀ sí nínú ohun tí ó ń sọ bíkòṣe ẹwà ojú rẹ̀ pẹ̀lú bí ètè òkè òun ìsàlè rẹ̀ ṣe ń ṣe n̄wẹ́lẹ́-n̄wẹ́lẹ́ tí ohùn tútù sì ń bọ́ lẹ́nu rẹ̀ bí ẹní mu omi inú àmù.
Mo dárúkọ mi fún un, èmi ọkùnrin mẹ́ta àtààbọ̀ òun náà sì dárúkọ rẹ̀. Ó ní "Àbẹ̀ní ni orúkọ mi" mo sì dá a lóhùn pé orúkọ tó dára ni orúkọ rẹ̀, kódà, ó fi í yangàn gẹ́gẹ́ bí ọmọ adúláwọ̀ tòótọ́. Mo nawọ́ mi láti bọ̀ ọ́ lọ́wọ́, òwọ́ rẹ̀ sì jẹ́pè ọwọ́ mi Láàárín ìsẹ́jú àáyá.
Mo kọjú síwájú láti fi iyè sí ohun tí olùkọ́ ń wí ṣùgbọ́n ọkàn mi kò kúrò lára àfín tó wọjà yìí. Orísìí èrò ni ó ń tawọ́-tasẹ nínú mi tí n̄ kò sì mọ ohun tó kàn láti ṣe. À fi bí ẹni pé n̄ kò bá obìnrin sọ̀rọ̀ ìfẹ́ rí. Kókó ohun tí ó gba ọkàn mi ni bí n̄ ó ṣe tún bá arẹwà yìí sọ̀rọ̀ àti pé bí n̄ ó ṣe rí nọ́ḿbà ẹ̀rọ ìpè Àbẹ̀ní gbà. Ọ̀rẹ́ẹ̀mi Sàámú tilẹ̀ ń pàkíyèsí mi sí ìbéèrè tí olùdánilẹ́kọ̀ọ́ ń bèèrè ti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sì ń já a gbà mọ́ ara wọn lẹnu. Ẹ̀rín ẹlẹ́rẹ̀kẹ́ ni mo fi dá a lóhùn bí ẹni pé ohun tó ń sọ yé mi. Bẹ́ẹ̀ n̄ kò jẹ́ kí ojú mi kó kúrò lára Àbẹ̀ní.
Aṣọ funfun tí kò ní apá gígùn ni Àbẹ̀ní wọ̀ ní ọjọ́ tí mò ń wí yìí. Ó sì wọ ṣòkòtò tírọ́sà aláwọ̀ yanrìn kànga. Ó lo aago ọwọ́ aláwọ̀ dúdú pẹ̀lú bàtà dudu lẹ́sè rẹ̀. Ọ́ gbé àpò ìkọ́pá rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ òsì. Àwọ báàgí náà bá àwọ ṣòkòtò rẹ̀ mu rẹ́gí. Irun òyìnbó aláwọ̀ dúdú ni ó wà lórí rẹ̀ ní ọjọ́ yìí. Kí n̄ má parọ́, Àbẹ̀ní rẹwà lóbìnrin.
Kò pẹ́ púpọ̀ ni mo sàkíyẹ̀sí pé ó ń palẹ̀mọ́ ìwé rẹ̀ tí ó gbé sórí tábìlì gbọọrọ iwájú rẹ̀. Mo yára bi í léèrè pé ṣé ìlọ ti yá nìyẹn? ní ohùn tútù bí i tútù ọ̀gẹ̀dẹ̀ ọ̀mìnì lofun adélébọ̀. Ó dá mi lóhùn pé òun ní iṣẹ́ mìíràn ní àsìkò náà. Mo fẹ̀sọ̀ béèrè ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó sì sọ ọ́ fún mi ní ẹyẹ ò sọkà. Mo béèrè nọ́n̄bà rẹ̀ pẹ̀lú ọkàn kan nínú olúwa. Sí ìyàlẹ́nu, ó fún mi. Mo fíláàṣì nọ́ńbà náà láti lè rí i dájú pé kò fún mi lófo kó tó dìde. Bí ẹ̀rọ ìpè náà ti wọlé ni mo sọ fún un pé "nọ́ńbà mi nìyẹn" . Inú mi dùn látorí dé fùrọ̀ ìdí, à fi bí ẹní jẹ lótò. Ọmọ ló dára tó yìí tí kò lábàwọ́n kankan tí kò sì kà á sí bàbàrà láti fún mi ní nọ́ńbà rẹ̀.
Ó yàtọ̀ sí Fọlákẹ́ afàkàbà-ṣe-ìbàdí, ó fẹ́rẹ̀ lé ní oṣù márùn-ún tí mo fi ń bèèrè nọ́ńbà ẹ̀rọ ìpè rẹ̀ kí ó tó wá fún mi. À fi bí ẹni pé okùn ẹ̀mí rẹ̀ ni nọ́ńbà ọ̀hún jẹ́. Òbùrẹ́wà òun pẹ̀lú wàhálà. Àmọ́ bí mo bá fẹ́ mú tẹ̀gàn kúrò, òhun náà rẹwà níwọ̀nba tí Adẹ́dàá fún un, ṣùgbọ́n ẹwà rẹ̀ kò wù mí bí i ti èyí tí ojú mi ṣẹ̀ṣẹ̀ gán-án-ní yìí. Ìgbà tí Fọlákẹ́ yóò fi fún mi ní ẹ̀rọ ìpè rẹ̀, ìfẹ́ rẹ̀ tilẹ̀ tí yọ lọ́kàn mi. Èsúrú rẹ̀ ṣàṣe jù, ó tẹ́ lọ́wọ́ oníyán mi.
Àbẹ̀ní dá gbére fún mi pé ó dìgbà lédè Gẹ̀ẹ́sì. Èmi náà sì dá a lóhùn bí ó ti ń dìde.
Bí ó ti dìde tí ó sì ń lọ ni mò ń fi ojú mi wò ó lọ. Káì, ká yọ tẹlẹ́gàn kúrò, Àbẹ̀ní dára. Ká tún fi tẹlẹ̀gàn ṣe, Àbẹ̀ní rẹwà. Ó pélẹ́ńgẹ́ níwọ̀nba, kò kúrú jù bẹ́ẹ̀ sì ni kò ga jù. Ó jẹ́ ọmọ tó nà láti òkè dé ìsàlè. Àkọ̀yìnsí rẹ dùn-un wò, ó sì mọ̀ ní ìwọ̀nba. Èèso méjì igbá àyà ọlọ́mọge rẹ̀ ti kúrò ní àgbálùmọ́ bẹ́ẹ̀ sì ni kò tó ti ìbẹ́pẹ. Ní ìwòye mi, ohun tí mo rí tí a faṣọ pọ́n dàbí ọsàn ìgbáha tó rẹ̀ dòdò. Ó yàtọ̀ sí ti ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́mọge òde ìwòyí. Ọ̀pọ̀ wọn ni eléjìrẹ́ wọn ti dàálẹ̀ bí ọwọ́ aago tí ó lu aago mẹ́fà ààbò ìrọ̀lẹ́ (6:30pm). Bí kìí bá ń ṣe ìrànwọ́ àgbékọ́ òyìnbó tí wọ́n fi ń kó àwọn eléjìrẹ́ wọn ròde ni, kín ni à bá tí wí? Kí Elédùà ó ṣàànú wa ni.
Àbẹ̀ní jẹ́ ẹni tó mọ́ lára, tí ó sì jọ̀lọ̀ láwọ̀. Ó mọ ẹsẹ̀ bàtà á gbé, ó sì mọ̀ ìrìn-ín rìn. Mo fi ojú sìn ín títí n̄ kò fi rí àkẹ̀yìnsí rẹ̀ mọ́.
Saintpradol❤️
ReplyDeleteÒşo mo gbé omo gbìn.....😘😘😘
Wow eleyii naa suwon
ReplyDeleteWow, this is lovely
ReplyDeleteGreat
ReplyDelete