ÀBÈNÍ
ÀBÈNÍ👸🏻💐
Orí kẹ́ta
Lágbo akadá
Ṣe bí ibi à ń lọ ò jìn rárá, ibi à ń yà sí ló pọ̀. Kìí kúkú ṣe pé mo ti yáa gbàgbé ibi mo ti mú ìrìn àjò ìtàn mi lórí bí mo ti pàdé ọmọbìnrin, ọ̀pẹ́lẹ́ńgẹ́, arẹwà, ẹlẹ́yinjú ìfẹ́, abeyín funfun nẹnẹ lábẹ́ ẹnu tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Àbẹ̀ní. Láti ọjọ́ tí mo ti rí i ni ọkàn mi kò ti kúrò lára rẹ̀. Ẹwà Àbẹ̀ní nìkan kọ́ ló mú ọkàn mi, sísọ̀ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde lénu dà bí ẹní ń da omi tútù sáyà ni. Ohùn rẹ̀ dùn lẹ́tí. Kí ènìyàn fi irúfẹ́ ohùn bẹ́ẹ̀ bú ìyá mi, pínrín, n̄ kò níí bínú sí i.
N̄ kò tilẹ̀ lè pe nọ́ńbà tó fún mi fún ìgbà pípẹ́ díẹ̀. Kò sí ohun tí ó fa èyí bíkòṣe àsìkò tí a wà ní ilé ìwé lásìkò náà. Ẹyin àgbà náà ló wí pé, bí igí bá ré lugi, tòkè rẹ̀ làá kọ́kọ́ mú kúrò. Àsìkò ìdánwò sáà Kejì ni. Mo tilẹ̀ ní isé àkànṣe tó pọ̀ níwájú mi lásìkò náà. Ọjọ tí mo pàdé rẹ̀ gan-an, n̄ kò lè lọ sí ilé rárá nítorí mo ní iṣẹ́ àmúrelé olósùkan lórí gírámà èdè Yorùbá tí ọkàn lára ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ èdè tí ó ń kọ wa ní sáà náà fún wa. Òwúrọ̀ ọjọ́ Kejì ni ọjọ́ tí wọ́n ní kí a mú un wá yóò péé. Mo ṣe àìsùn mọ́jú ọjọ Kejì ni. Ọ̀pọ̀ àwọn asíwájú wa ni wọ́n wà ní inú iyàrá ìkàwé ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ wa ni òrúmọ́jú yìí. Ọmọọdẹ, Olórí Ọ̀dọ̀, Fílíìpì, ẹ̀gbọ́n Ṣẹ́gun ọmọ Ògúndèji, Ifá,Súrì, omidan Fúnmiláyọ àti omidan Títílayò ọmọ Adétọ̀nà. Ẹsin kìí kọ eré àsálọọlé ni wọ́n wá fi òru yìí se láti lè parí iṣẹ́ ìwádìí ọlọ́dún kẹ́rin wọn.
Àwọn akẹgbẹ́ mi tilẹ̀ pọ̀ tí wọ́n wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Mo tilẹ̀ rántí , Aṣáolú, Àbáàsì, Sàámú Ògbó, Áléẹ̀sì, Pẹ̀lúmi ọmọ Ọláníhún, Olóyèédé, Àdùnní ọmọ Rùfáí, Yẹ́misí, Róòsì, Títílayò ọmọ Ògúnrùkù àti Kàbírá. Lọ́rọ̀ kan, a pọ̀ lálẹ́ ọjọ́ yìí tí a kò lọ ilé.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Ṣẹ́gun Àkíìmù ọmọ Sàláù kò gba gbẹ̀rẹ́ rárá. Ọmọ bíbí ìlú Ìbàdàn ni. Wọ́n kórìíra ìmẹ́lẹ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ tí ó yan ìwé rẹ̀ nípọ̀sì. Wọ́n ní ẹ̀bùn kí wọ́n mọ orúkọ akẹ́kọ̀ọ́ tí ó bá ti gba abẹ́ wọn kọjá. Wọn Kìí ṣe onírìkísí tàbí agbàbẹ̀tẹ́lẹ̀ ènìyàn. Ilé ìwé yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ ni àwọn náà ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè títí wón fi dé ìpele à ń kọ́ni. Wọ́n tilẹ̀ máa ń sọ ohun tí ojú àwọn rí kí o to di pé àwọn dé ipò tí àwọn wà yìí. Ìyà tí àwọn jẹ nígbà tí ojú wà lórúnkún lásìkò ti wọn láti lè kàwé ní Ìbàdàn.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Ṣẹ́gun Àkíìmù ọmọ Sàláù a máa dúpẹ lọwọ olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ fún ipa ribiribi tí wọ́n kó lórí ìṣẹtò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ nígbà ayé wọn. Wọn á ní, bí kìí bá ṣe ti wọn, àwọn kì bá má ti rí àǹfààní àti kàwé nítorí ìdílé tí wọ́n ti jáde wá. Ọlọ́mọ púpọ̀ ni bàbá wọn tí wọn jẹ́ aláàbò ìlú fún ìjọba (ọlọ́pàá). Ilé olórogún ni wọ́n ti tọ́ wọn dàgbà. Wọ́n kún fún ọgbọ́n orí àti inú pẹ̀lú. Ìyàwó kan ni wọ́n fẹ́ tí wọn sì rí ayọ̀ ìgbéyàwó wọn. Wọn a ní, bí kìí bá ṣe ti Olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ tí ó ṣètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́, ẹlẹ́ran tàbí iṣẹ́ à ń gbà gáráàjì ni àwọn ìbá máa ṣe ní Ìbàdàn. Wọ́n ní ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ yìí ló ran àwọn lọ́wọ́ láti lè kàwé yanrann̄tí.
Bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Ṣẹ́gun Àkíìmù bá kẹnu bọ ìtàn wọ́n fún wa. Inú wa máa ń dùn sí i láti gbọ́ ó. Àwọn àgbà kú bọ̀, wọ́n ní, afọgbọ́n ọlọ́gbọ́n ṣọgbọ́n ni kìí jẹ́ ká pe àgbà ní wèrè. Wọ́n tilẹ̀ sọ fún wa pé àwọn àti Ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ èdè Abídèmí Fẹlíìsì ọmọ Fábùnmi jọ ka másítáàsì wọn ni. Wọ́n ní nígbà náà, ibi ti awọn ti máa fẹsẹ̀ rìn wá kò kéré níye láti wá sí iyàrá ìkẹ́kọ̀ọ́. Síbẹ̀, àwọn kìí pẹ́ẹ́ dé tàbí pa kíláàsì jẹ.
Ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ mi ní abala gírámà èdè Yorùbá ni Ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ èdè Abídèmí Fẹlíìsì ọmọ Fábùnmi jẹ́. Láti sáà kínní ìpele kìíní ni wọ́n ti ń kọ́ mi. Wọ́n mọ ìwé, ìwé sì mọ̀ wọ́n. Ní kúkurú èdè, àwọn méjèèjì mọ ara wọn. Ilé ìwé yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ ní àwọn náà ti ka ẹ̀kọ́ gíga ọlọdún mẹ́rin ti wọn, àwọn ló tilẹ̀ jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tí ó peregedé jù lọ ní ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ wòn lásìkò ti wọn. Ọmọ bíbí ìlú Èjìgbòmẹkùn ni wọ́n.
Nígbà tí yóò fi di aago márùn-ún, mo parí iṣẹ́ àṣetiléwá mi. Mo wó lulẹ̀. N̄ kò tilẹ̀ rántí pé mo pàdé ọmọge kankan rárá mọ́. Nígbà tí àwọn tí ọ́ ń tún iyàrá ìkàwé ṣe dé láti gbá ibẹ̀ ni wọ́n jí mi ní ọwọ́ agogo méje kọjá ìṣẹ́jú péréte. Bí ará ti ń dùn mí bẹ́ẹ̀ ni orí ń fọ́ mi. Mọ já ìwẹ́ láti gba iṣẹ́ àṣetiléwá gbogbo awọn akẹgbẹ́ mi sí gẹ́gẹ́ bí aṣojú wọn àti ìlànà tí olùkọ́ ní kí a tẹ̀lẹ́.
Ọ̀kan lára akẹgbẹ́ mi Àbáàsì ọmọ Núrùdíìni tilẹ̀ ti parí iṣẹ́ àṣetiléwá tirẹ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ méjì nínú osù kan tí wọ́n fún wa. Ó jẹ́ ẹní tí ó já fáfá lẹ́nu ẹ̀kọ́ rẹ̀. Kìí fi ọ̀rọ̀ ìwé ṣeré rárá. Ó tilẹ̀ máa ń sọ pé ìwẹ́ jẹ́ ayé òun. Kò sí ẹni tí kò mọ ọmọ Núrùdíìnì ní ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ mi. Bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí mọ̀ ọ́n, bẹ́ẹ̀ náà ni ó jẹ́ ààyò láàárín ọ̀pọ̀ olùkọ́ ibẹ̀. Ààfáà ni ìnagijé rẹ̀ nítorí yàtọ̀ sí pé ó jinlẹ̀ nínú ẹ̀kó rè. Ó tún ní ìmọ̀ tó kún nínú ẹ̀sìn Mùsùlùmí. Aláwàdaà ènìyàn ni, kìí sìí fi inú rẹ̀ ṣeré.
Àṣe-kú-dórógbó ni mo ṣe súlè ọjọ́ Kejì yìí. Láti iṣẹ́ akadá kan sí òmíràn. Láti iyàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ kan sí èkejì. Nígbà tí mo máa fi jàjà délé. Mo ti wá n̄ǹkan fi panu ní ọ̀nà. Mo fò sórí ìbùnsùn mi bí i ẹni wọ́n wí fún pé; ọkọ mi kò sí nílé, sáré ṣehun tí wàá ṣe. Mo Sùn lọ bí ajá tí wọ́n fín nígbó. N̄ kò tilẹ̀ lá àlá débi pé má rí Àbẹ̀ní lójú àlá mi ní alẹ́ ọjọ́ náà. Àsùn yakata Ni mo sun oorun náà títí ilé ọjọ́ Kejì fi mọ yáúyáú. Kìí ṣe pé ìfẹ́ Àbẹ̀ni ti kúrò lọ́kàn, ó kàn rẹ ara ni. Kódà, ó rẹ ọpọlọ tíí mú ará ṣiṣẹ́ mi pẹ̀lú.
© Saintpradol


Keep flying bro
ReplyDelete