ALÁǸTÉRÉ



        ìtàn mi dá lé ọmọbìnrin aláìgbọnràn kan tí orúko rè ń Àǹtéré.

        


    Ní ìlú kan ní ayé ìgbà kan, ìsẹ̀lẹ̀ àjálù ń selẹ̀ ní ilù tí a kò dá orúkọ rẹ̀. Ọbá pe àwọn aláwo ìlú, àwọn aláwo náà sì sọ fọ́ba àti aráàlú pé ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ lọ sí odò ìlú láti lọ ṣe ohunkohun fún ọjọ́ méje kí àjálù náà bá lè dáwọ́ dúró.

     Gbogbo ìlú ti múra sílẹ̀ di gbogbo ọjọ́ yìí. Wọ́n pọn omi tó máa tó wọn lò fún ọjọ́ méje. Ìséde sì wà fún gbogbo ọjọ́ méjèèje fún gbogbo ìlú,kí a má ba rí ẹni tó máa dẹ́jàá.

     Lẹyìn tí orò ìlú bẹ̀rẹ̀, ní ọjọ́ kéje ni Aláǹtere fárígá fún àwọn òbí rẹ̀ pé kí wọ́n fún òhun láàyè láti lọ sódò lọ wẹ̀. Àwọn òbí rẹ̀ bẹ̀ ẹ́, wọ́n sì tún rọ̀ ọ́, kò gbọ́ àfi ìgbà tó tẹ́fẹ̀ẹ́ inú rẹ̀.

      Nígbà tí Aláǹtéré dé odò, ó wọ̀tún-wòsì, kò rí enì kan, ó bọ́ sódò, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní fomi ṣanra.Inú rẹ̀ ń dùn bí ó ti ń ṣe èyí láìmọ̀ pé ohun tó dùn níí pani.

      Kò pẹ́ bí ó ti ń wẹ̀ lọ́wọ́ ni Olúwẹri yọ sí í (Ebọ̀ra odò). Olúwẹri bínú sí ọmọ aláìgbọnràn yìí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní wọ́ ọ lọ sí ìsàlè odò. Bí Olúwẹri ti ń wọ́ Aláǹtéré lọ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ní kọrin pẹlú àbámọ̀ tí ó sì ń bẹ Ẹbọra odò kí ó má wọ́ òun lọ. Báyìí ni ó sì ṣe kọ ọ́:


Lílé: Aláǹtéré o

Ègbè:Àǹtéré

Lílé:Aláǹtéré ọ

Ègbè:Àǹtéré

Lílé: Ìyá ni bomilé ṣanra 

Ègbè:Aláǹtéré

Lílé: Mo lémi kò bomilé ṣanra

Ègbè: Aláǹtéré

Lílé: Bàbá ni bomilé ṣanra 

Ègbè:Àǹtéré

Lílé: Mo lémi kò bomilé ṣanra

Ègbè:Àǹtéré

Lílé: Ìyá ni bomilé ṣanra 

Ègbè:Àǹtéré

Lílé: Mo lémi kò bomilé ṣanra

Ègbè: Àǹtéré

Lílé: mo dódò mo bóluwẹri 

Ègbè:Àǹtéré

Lílé: mo dódò mo bóluwẹri

Ègbè:Àǹtéré

     Bí Àǹtéré ṣe ń kọrin yìí pèlú omi lójú tí Ẹbọra yìí kò sì gbọ́ ìpẹ̀ rẹ̀.

Ìpèdè ìparí àlọ́

Apàló: Ìdí àlọ́ mi rè é gbáńgbáláká,

            Ìdí àlọ́ mi rè é gbàǹgbàlàkà

           Bí mo bá dé ìdí ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹẹrẹ

           Kí n bá wọn bímọ wẹẹrẹ

           Bí mo bá dé ìdí ọ̀gẹ̀dẹ̀ gbàǹgbà

           Kí n bá wọn bímọ gbàǹgbà

           Bó bá ṣe irọ́ ni mo pa,

           kí agogo ẹnu mi má rò ó

Comments

Post a Comment

Popular Posts