THE STORY OF ÀBẸ̀NÍ👸🏻💐
ÀBẸ̀NÍ👸🏻💐
Orí kejì
Láàárín àwọn ọkùnrin
Lẹyìn tí a parí ìdánilékòó, n̄ kò lè pa ìdùnnú ohun tí ó ń lọ lọ́kàn mi mọ́ra. Mo sọ fún ọ̀rẹ́ mi pé ṣé ó ṣàkíyèsí ọmọbìnrin tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi? Ó ní " ọmọ náà rẹwà náà, ṣé ẹ gba nọ́ńbà rẹ̀"? Mo rẹ́rìn-ín. Sàámú ní " Mo jẹ́rìí yín". Mo dá a lóhùn pé mo fẹ́ràn ọmọbìnrin yìí gan-an ni o. Sàámú wí fún mi pé bí mo ti má ń sọ nìyẹn, kò kọjú. Mo rẹ́rìn-ín. Mo ní awo ló ráwo, òun náà sì kú sí ẹ̀rín.
Lóòótọ́ ọ̀ṣọmọ ni Sàámú Ògbó, àkíìkà, Òjẹmẹ́ta-ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀-ní-òòjọ́-fi-mẹ́ta-àti-ààbọ̀-panu-mọ́jú. Ọkùnrin mẹ́ta àtààbọ̀ àyànfẹ́ ọlọ́mọge.Bí Sàámú bá ń pe ewé kan obìnrin, igba ewé wọn ló máa ń jẹ́ ẹ lójú ọlọ. Ọmọ Ògbó ṣẹ̀ṣẹ̀ pàdé ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ ọlọ́mọge kan ni, Tèmítọ́pẹ́ ni orúkọ rẹ̀ ń jẹ́. Ìfẹ́ Olúwatèmítọ́pẹ́ ti wá mọmú láyà ọmọ Ògbó tó fi jẹ́ pé kò lè wo ojú obìnrin mìíràn mọ́. Kò sẹ́ni tí kò lè ní ìgbà ọ̀tun. Ìfẹ́ Àbẹ̀ní ni mo fẹ́ kó ṣe òkùnfà tèmi bí i ti Olúwatèmítọ́pẹ́ ṣe jẹ́ òkùnfà ti Sàámú . N̄ ó tún máa sọ̀rọ Sàámú àti ìfẹ rẹ̀ níbi tí wọ́n bá a dé lónìí, ìyẹn tí ààyè bá gbàmí nínú ọ̀rọ̀ mi.
Kí n̄ má bókùú lọ ilé olórò. Èmi kò fi taratara fẹ́ràn ọbìnrin, ṣùgbọ́n mo fẹ́ràn kí n̄ máa yẹ́ arẹ̀wà sí ni. Bí ọmọ́ bá dùn , ó yẹ ká wí. Bí ènìyàn kò bá sọ, Èdùmàrè tí ó dá arẹwà náà yóò nínú sí onítọ̀ún. Kí Èdùmàrè má jẹ́ á kó sí páńpẹ́.
Ó tilẹ̀ ní ọ̀rẹ́ mi Yùsúfù, Àlàó làkọ pàrá, yí ó bàyá ọmọ tí a bí lọ́jẹ̀ tí ò lè sawo, ṣòkòtò já níbàrá ìdí ọkọ ọlọ́mọge, òdọ́mọ-dóyà ọmọ Àláájì ní Ìbàdàn. Ọ̀rẹ́ mi fẹràn obìnrin, àwọn obìnrin sí fẹ́ràn rẹ̀. Ọkùnrin kan tí ń fi ọ̀pá kan da igba màlúù, ọmọ dúdú bí i kóró isin.
Aláfẹ́ ènìyàn ní Yùsúùfù jẹ́, ó tutù lójú kìí sì í ṣe onípàńle ènìyàn. A jọ wà ní ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ kan náà ni nígbà tí a wọ ilé ẹ̀kọ́ gíga tí mo wà yìí, kí bàbá rẹ̀ tó ní àwọn kò fọwọ́ sí i kí ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Yorùbá. Lọ́rọ̀ kan, ó mú iṣé mìíràn lẹyìn pípààrà ọ́fíìsì olórí ẹ̀ka ẹ̀kọ́ nígbà náà Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọlátẹ́ju àti akitiyan àwọn tó wà láágbọn àyípadà iṣẹ́ a wá kọ́.
Mo sì lẹ̀ rántí alẹ́ ọjọ́ ìfinimọ́lẹ́ wa nígbà tí a wà ní ọdún kìíní. Èmi àti Àkànní ọmọ Ẹgbẹ́làdé alóbìnrin-lákàá-bí-ẹni-ń-lágbàdo àti àwọn obìnrin mẹ́ta tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ ni a jọ gbéra kúrò nínú ilé wa sí inú ọgbà ilé-ìwé ní alẹ́ ọjọ́ náà. Nígbà tí a óò fi dé gbọ̀ngàn ibi àríyá, olórin ti ń ju gbẹ̀du sílẹ lórísirísi tí àwọn ọmọge onírúurú àti àwọn ọkùnrin jáńtìrẹrẹ ń sòdí bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n ń jan ẹsẹ̀ mọ́lẹ̀.
Mo ti pe Sàámú kí ó bá èmi ,Àkànní ọmọ Ẹgbẹ́làdé àti àwọn ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ mẹ́ta gba ààyè sílẹ̀ ní ọwọ́ iwájú. Bí a sì ti ń dé gbọ̀ngàn náà ni àwọn obìnrin wọ̀nyí tí rí àwọn ọ̀rẹ́ wọn, tí wọ́n sì tẹ̀lé wọn.
Àkànní pé Ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ nígbà náà, tí ó ti ń dúró dè é kí àwa tó dé pé òun tí wà níbẹ̀, kò pẹ́ ni ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ de, ọmọ náà kò kúrú jù bẹ́ẹ̀ sì ni kò ga, ó jẹ́ ọmọ tí ó ki bí i bìí kékere ìgbàrìgbá, igbá àya rẹ̀ nípọn ẹ̀yìn rẹ̀ kò sì bùáyà jù. Òun àti alábàgbé iyàrá rẹ̀ ni wọ́n jọ wá. Mo kí Tóbi tó jẹ́ alábàgbé ọ̀rẹ́bìnrin Àkànní nítorí a jọ wà ní ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ kan náà ni, Àkànní sì fi ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ hàn mí. "Ọlámìídé lè mi ń jẹ́" mo wí bẹ́ẹ̀ fún un, ó sì ní Búkì ni orúkọ òun. A bọ ara wa lọ́wọ́ gbogbo wá sì wọ inú gbọ̀ngàn àríyá padà. Wọ́n ti lẹ̀ dáwa dúró láti wo ìwé àṣẹ fún wa láti wọlé láìsan owó ẹnu ọ̀na kí a tó wọlé.
Kò pẹ́ púpọ̀ tí a wọlé ni a ti rí Sàámú pẹlú ife àdàlú ọtí lọ́wọ́, ó ń pè mí pé láti fi ibi tí òun bá wa gba ààyè sí hàn mí. Ó ní ìgbà tí a kò tètè dé ni ààyè ènìyàn márùn-ún tí òun gbà ti di méjì. Kò sí ààyè míràn mọ́ ní àsìkò tí mò ń wí yìí. Gbogbo inú gbọ̀ngán ti kún. Àkànní jókòó, ó sì gbé ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ Búkì sẹ́sẹ̀. Èmi náà jókòó, Tóbi sì jókòó sí ẹsẹ̀ mi. Sàámú jókòó sí ilà kẹ́ta sí àwa ní ẹ̀yìn òun àti ọmọbìnrin kan tí ọ̀rọ̀ wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ jọ wọ̀ ní àsìkò ìgbà náà. Ẹ jẹ́ kí n̄ fi orúkọ bò ó lásìírí. Ọpọ̀ àwọn tí wọ́n jókòó sí ìtòsí mi ní a jọ jẹ ọmọ ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ kan náà, a kí ara wa. Ṣàámú tilẹ̀ fi otí tí ó ń muu fi lọ̀ mí. Kíákíá ni mo gbọn orí jégé pé n̄ kò mu. Ó ní kọ̀ le korò tàbí pa ènìyàn nítorí àwọn dà á pọ̀ mọ́ kóòkì ni.
Nígbà tí wàhálà rẹ̀ fẹ́ pọ̀jù, mo gbà á lọ́wọ́ rẹ̀, mo gbẹ́e dání. N kò mu ún. Mo ní kí Tóbi dìde lórí ẹsẹ̀ mi pé, mo fě wá ọ̀rẹ́ẹ̀mi kàn lọ. Mo dìde pẹ̀lú ọtí ọ̀hún nínú ife lọ́wọ́ mi, mò ń wò yíká bí Tófúnmi Àjíkẹ́ bá wà nínú gbọ̀ngàn ọ̀hún.
Akẹgbẹ́ mi ni Àjíkẹ́, Ó jẹ́ ọmọ tí ó níwà mọ́ ẹwà, bí ẹja ńlá bá sọ nínú ibú, àwọn àgbà òfìwọ̀ wọn yóò mọ iye tó tó. Eléjìrẹ́ iwájú Àjíkẹ́ kún nínú ìjáàbù, ẹ̀yìn rẹ̀ náà ò sì ṣọmọ nù, ó mọ́ lára rẹ́súrẹ́sú, ó sì ṣe rùmúrùmú. Mùsùlùmí ni, ó sì fi í hàn. Láìwo tẹ̀sìn rara bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé onígbàgbọ lè mi. Mo fẹ́ràn rẹ̀ gidigidi ni àsìkò ìgbà náà tí a wà ní ọdún Kìíní. Gbogbo akitiyan mi láti jẹ́ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀, pàbó ló já sí. Ó ni ẹni tí yóò yan òun ní ọ̀rẹ́bìnrin gbọ́dọ̀ lè ní ìpinu pé òun yóò fẹ́ òun sílé bí àsìkò nìkáì bá pé láti re ilé ọkọ. Èyí kò bà mí lẹ́rù rárá nítorí ẹni bá fẹ́ joyin inú àpáta kìí wẹnu àáké. O ní bàbá òun kò ní gbà kí òun fẹ́ ẹlẹ́sìn mííràn tó yàtọ sí Mùsùlùmí. Kò sí ohun tí n̄ kò sọ tán. Ẹ̀yìn igbá ni gbogbo rẹ̀ bọ́sí. Mo sọ fún un pé n ó wàá sí ibi àríyá alẹ́ náà, ṣùgbọ́n ó ní òun kò mọ̀ bóyá òun yóò wàá tàbí òun kò ní wá.
Bí mo ti ń wá a, mo pàdé ọ̀kan lára akẹgbẹ́ mi kan lóbìnrin. Ó ní òun ti ń jó láàárọ̀, ọ̀rùgbẹ sì ń gbẹ òun. Mo ní kò sí omi lọ́wọ́ mi àyàfi ọtí yìí. Ó gbà á, ó sì da ìdajì rẹ̀ sọ́fun gọ̀rọ̀gọ̀. Ó bá tirẹ̀ lọ. Tí mo ní kí n yídà ni mo pàdé Kílẹ́ àti Ọmọowó ọ̀rẹ kòríkòsùn rẹ̀. Kílẹ́ rọ ọtí àdàlù tí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ dáwó rà sínú ààbò àdàlù ọtí tí ó wà lọ́wọ́ mi. Àdàlù ọtí pọ̀mọ́ àdàlù mííràn, ẹní bá mu ún rí ní yóò mọ bó ṣe máa rí lọ́fun. Mo gbé ọtí dání, mò ń wá Tófúnmi Àjíkẹ́ kiri.
Nígbà tí mo rìn sàà sí ọwọ́ ẹ̀yìn díẹ̀, yóò ti tó àgogo kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní àkókò tí mò ń wí yìí. Níbi tí mo ti ń wá Àjíkẹ́ kiri. Mo pàdé ọmọbìnrin kan tí ó máa ń ta oúnjẹ ní iwájú ilé ìgbé mi nígbà tí mo wà ní ọlọ́dún kìíní. N̄ kò tilẹ̀ mọ̀ pé akẹ́kọ̀ọ́ ọlọdún kìíní ni òun náà. Ó jọ bí ẹni pé ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sí ibi àríyá alẹ́ náà ni. Ọjà tí ń bẹ lára ọmọ yìí. Ṣàṣà ni ọkùnrin tí yóò rí i tí kò ní fẹ́ kówó lé e. Eléjìrẹ́ ẹ̀ tọ́ ìrọ̀rí báálé, ó sì rí ara fi gbé e. Ìbàdí arẹwà yìí , gan-an ni à bá máa pè ní àrímáleèlọ̀-àwòpadà-sẹ́yìn. Kò sí gbogbo ìgbà tí ojú mi bá gán-án-ni ìbàdí àrán yìí tí àyà mi kìí sọ kìjí. Yàtọ̀ sí gbogbo àwọn àlùmọ́nì ẹ̀wà ara ọmọbìnrin tí Adẹ́dàá fún ọmọbìnrin yìí. Ó tún ní ẹ̀wa ojú, ó sì tún mọ ará mú pẹ̀lú. Bí ó bá múra tán, ó máa ń dàbí ọbẹ̀ Àlàhájà ní ìparí ààwẹ̀. Ní alẹ́ àríyá yìí, ó àṣọ̀ gáùn aláwọ̀ pupa ti òdòdò róòsì. Ó ṣe Irun tí ọwọ́ rẹ̀ gùn dẹ́bàdí. Mo sún mọ́ ọn. Mo kí i, mo sì bi pé kó jẹ́ ká jọ jó. Ó ní rárá, ó sì bá tirẹ̀ lọ. Ṣèbí mo fẹ́ fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe bí a ò bá rí àdán, àá sì fi òòbẹ̀ ṣẹbọ. Ó dùn mí díẹ̀, mo sì tẹ̀ ẹ́ síwájú wíwá Àjíkẹ́.
Wùmí Ọ̀rẹ́bìnrín Sàámú tilẹ̀ pàdé mi. Ó ní ṣé mo bá òun rí Sàámu mo sì dá a lóhùn pé n̄ kò mọ ibi tí Sàámú kí awo má ba ya. Obìnrin Méjì tilẹ̀ ti pàdé fún Sàámú lóru àríyá yìí tí Sàámú sọ fún mi kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́. Bí Wùmí alálọ̀ọ́mọ́ bá tún fi gán-án-ní rẹ̀, á jẹ́ ẹni máa kú pàdé ẹní máa pá nìyẹn.
Nígbà tí mo wá Àjíkẹ́ títí, tí n̄ kò sì rí i. Mo padà síbi mo jókòó sí. Nígbà tí mo máa fi dé ibẹ̀ n̄ kò bá Tóbi mọ́ lórí ààyè tí mo fi í sí. Òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti jáde. Mo bá ọ̀kan lára àwọn akẹgbẹ́ mi lórí àga mi. Ráfá ni orúkọ rẹ̀. Ọ́ gba ọtí ọ̀wọ́ mi, ó sì da gbogbo rẹ̀ mu tán yán-an-yán-an. Mo ní kí ó dìde láàyè mi, ó yarí pé òun kò ní dìde àfi tí n̄ ó bàá gbé òun sí ẹsẹ̀. Kò sí ṣíṣe, kò sí àìṣe. Mo gbà láti gbé e sẹ́sẹ̀. Ráfá wọ ṣòkòtò dúdú àti aṣọ funfun, kò kúrú bẹ́ẹ̀ sì ni kò ga púpọ̀. Ó jẹ́ ọmọ tí ó mọ́ lára, ó sì ṣe rùmúrùmú. Ó dìde, mo jókòó, ó sì jan ìdí mọ́ mi lẹ́sẹ̀. Mo pariwo, "ó pọ̀". Gbogbo wa tí a wà níbè sì rẹ́rìn-ín.
Kò pẹ́ rárá tí mo ti ṣàkíyèsí pé, àdàlù ọtí ti bẹ iṣẹ́ lára Ráfá. Ara rẹ̀ gbóná wá láti inú aṣọ bí ẹní ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ pé òun lu ìgbàdì ààrùn kòrónà. Ó ń nà pọ̀n-ọ̀n lẹ́sẹ̀ mi. Ojú rẹ̀ pọ́n bí iná àbẹ́là. Mo mọ̀ pé alákọrí ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lára Ráfá. Mo tún wọ́ ọ mọ́ra dáadáa. Mo fọwọ́ gbá ìbàdí rẹ̀ mú kí ó má ba à jábọ́. Gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ kọ́ ni mo lè sọ tán, kí ènìyàn má dà bí onísọkúsọ. Onísọkúsọ kú sì dára ju oníṣekúṣe ní ọgbọ́n ọmọdé tèmi. Èmi àti Ráfá ń mì lẹ̀ǹgbẹ̀ bí ẹni ọtí jọ ń pa.
À ṣẹ́ gbogbo bí mo ti ń bá Ráfá ṣeré, n̄ kò mọ̀ pé Yúsúfù Àlàó ń wò mí. Ó fọwọ́ tọ́ mi láti ẹ̀yìn. O ní kí n̄ sí Ráfá sílẹ̀ fún òun tí ó bá di àsìkò ijó lẹ́yìn ètò àríyá yìí. Àsìkò ijó yìí ni ọ̀pọ̀ àwọn tó wá síbi àríyá alẹ́ máa ń dúró dè. Olórin yóò máa gbé orin àjó-sọ̀bàdí-nù-ṣọmú-gen̄ge sí lọ́kan ò jọ̀kan. Àsìkò yìí, wọn yóò ti pa iná tí ó lè jẹ́ kí ó rí ojú ẹní wà níwájú rẹ̀. Bìlísì iná tí yóò máa kọ màlàmàlà fún ẹwà agbo ijó nìkan ló wà fún. Ẹ wá wo bí ọlọ́mọge ẹlẹ́jẹ̀tútù òun ọ̀dọ́kùnrin ti ń gbé e sún mọ́ ara wọn ní pẹ́kí-n̄-rẹ́kí, ní pẹ̀kí-n̄-rẹ̀kí. Àwọn òbí wa nílé kò kú gbọdọ̀ mọ̀ pé à ń dán irú èyí wò tán.
Àlàó sàlàyé fún mi pé òun ti bá Ráfá ní àsọtì pé àwọn yóò pàdé ní àsìkò náà. Mo sì sọ fún un pé kò burú. Yúsúfù, ọmọ Àlàájì nigboro Ìbàdàn tí yó ni àsìkò tí à ń sọ yìí. Bí ó ṣe padà jókòó, dẹ̀ẹ̀rẹ̀ ni ó ń wò bí ìyá àgùntàn. Ó sì ń bóyín bí ẹni ń jẹrú lọ́wọ́. Alẹ́ ọjọ́ Kejì tí Yúsúfù wálé mi ni ló ní motó mọ iye ohun tó dà lura tí ó fi ń wò bẹ́ẹ̀.
Àlàó làkọ pàrá fúnra rẹ̀, ṣòkòtò já níbàráàdí ọkọ ọlọ́mọge, ọlọ́pàá kan ìsàlẹ̀ ọ̀hún tí kò sí ihò tí kò le wọ̀. Ẹ̀rù Àlàó bà mí lórí ọmọ méjì kan tí ó ta mọ́ ọn láti ọ̀dọ̀ Sàámú Ògbó, okùn lẹ́ńgẹ́ gbéná wọlé àfẹ́sọ́nà Tèmítọ́pẹ́. Ọdún méjì ni ó fi wà pẹlú ìkan nínú wọn. Fún ọdún méjì yíì, áá máa wọlé ní àsìkò tó bá wù ú nítorí ó ti já ọmọlọ́mọ ní kọ́kọ́rọ. Àlọ́mọ́ ọmọgẹ ọ̀hún pọ̀jù. Bó ti ń forí ṣe fún Àlàó náà ní í fọrùn ṣe. Ó dà bí ẹni pé ìyá rẹ̀ rí já jẹ diẹ̀. Ọmọge yìí ò lálàsẹ́ owó, ó sì fi mọ ọ̀rẹ́ mi Àlàó. Sùgbón èyí ò ní kí ọ̀rẹ́ mí jáwọ nínú àíwòta. Ṣe bí, bí wọ́n kú ṣe pàdé nìyẹn kí ọ̀rọ̀ wọn tó wọ̀. Ìjà má sọ́ mi ló dé sí àárín àwọn méjèèjì lẹ́yìn ìgbà tí ọmọge yìí ká ọ̀rẹ́ mí pé ó tún ní obìnrin mííràn. Éjìro ní orúkọ ìyẹ̀n ń jẹ́. Ọmọ Íbò ni. Ọ̀rẹ́ mi a máa ròyìn rẹ̀. Kò tún nílò kí n̄ máa ṣàlàyé itú tí ọmọge Kalabá máa ń pa lórí pápá ìseré lákọlábo. Láti Mòro ni ó ti máa ń wọ ọ̀kada wá gbé kiní tí à ń wí yìí ká ọ̀rẹ́ mi mọ́lé.
Ìjà yìí ló mú kí Yùsúfù Àlàó pàdánù ọmọge alálọ̀ọ́mọ́ sọ́wọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan tí ó finú hàn lásìkò ìjà náà. Ọ̀rọ̀ ọ̀hún wá di olè gbé e, olè gbà á. N̄ kò lè sọ gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ náà tán. Bó yá tí ọ̀rọ̀ mi bá tún gba ibẹ̀, n̄ óò tún yán díẹ̀ fún un yin. Àti pé, àwòfín níí ba ojú èré jẹ́. Èyí tí mo wí náà ní jẹ́ òhun.
Nígbà tí àsìkò ijó ọ̀hún to, ẹbí ti ń pa mí, mo gbé oúnjẹ tí wọ́n pín nínú gbọ̀ngàn ọ̀hún nínú àríyá yìí, mo ké sí Àlàó, kí ó wá mú n̄ǹkan rẹ̀ sọ́dọ̀. Àlàó fa Ráfá dìde kúrò lẹ́sẹ̀ mi, ọ́ mú un lọ sí ojú agbo wọ́n jọ ń jó.
Gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní òru mọ́jú ọjọ náà kọ́ ni mo lè ròyìn. Ìwọ̀nba tí ojú mí rí gan-an ó gbẹnu tán. Mo fi gbọ̀ngàn náà sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi kan. A jọ lọ jẹ ìrẹ̀sì àti ẹ̀ran tí wọ́n fún wa, pẹ̀lú omi ọlọ́ràá.
Lẹyìn èyí, mo wá ibi mo lè forí pamọ́ sí di ilẹ̀mọ́. Agogo méje ti fẹ́rẹ̀ẹ́ lù kí n tó tají pẹ̀lú lala lẹ́nu. Mo kọrí sílé. Bí mo ti Délé, lẹ́yìn tí mo ti bọ́ bàtà àkúbè ẹsẹ̀ mi. Mo fò sórí ibùnsùn mi. Agogo mẹrin ku ìsẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún ni mo tóó ta jí.
©saintpradol


Love is a beautiful thing
ReplyDelete