ORÍKÌ ÌLÚ MI

          ORÍKÌ ÌLÚ ILÉ-IFẸ̀


Àbú ìtẹ́ní

Onífẹ̀ abùré

Ọmọ adádé owó rẹ̀mọ

Ọmọ olówó ìṣẹ̀ǹbáyé 

Kówó sílè tó gbòde.

Ọmọ akábọ́ owó rẹmọ.

Ọmọ Oòduà.

Ọmọ Ifẹ̀ Oòyèlagbò.

Àbú ọmọ olúfẹ̀ ìwọ là ń kéé sí

Wọn kìí dúró kí wọn nífẹ̀ Ọọ̀ni.

Wọn Kìí bẹ̀rẹ̀ kí wọn nífẹ̀ Òòrè.

Kò ga kò bẹ̀rẹ̀ ni wọ́n fi ń kí wọn nífẹ̀ Oǹtólú

Ẹní dúró kí wọn nífẹ̀,

Ẹbọra burúkú ló bọ́ ọ láṣọ.

Mo dúró mo kí wọn nífẹ̀ Ọọ̀ni

Wọn ò fi mí ṣẹbọ.

Mo bẹ̀rẹ̀ kí wọn nífẹ̀ Òòrè 

Wọn ò fi mí ṣètùtù.

Àìkí wọn nífẹ̀ o ò tábẹ́rẹ́

Ojúrábẹsá àwọn baba ẹ̀yìn ẹbọ ni wọn máa ń firú wọn ṣe.

Àbú ọmọ olúfẹ̀ ìwọ ni mò ń kí

Ọmọ olódò kan òtéréré.

Ọmọ olódò kan ọ̀tàràrà.

Odò tó ṣàn wéréke wérekè 

Tó déyìnkùlé Ọṣinlẹ̀ tó dàbàtà

Onípélé wọn ò gbọ́dọ̀ bù mu.

Alábàjà wọn ò gbọdọ̀ bù wẹsẹ̀.

Kìkìdá onísọ̀bọ̀rọ́ ní ó momi odò náà gbẹ

Ojúrábẹsá ìwọ ni mò ń kéé sí.


Òwúrọ̀ ọlọ́jọ́ 

Ẹmu ni wọ́n fi ń mu nífẹ̀ o jàre.

Kin ní mẹ́sàn kan ní í múlé Olúfẹ̀ wù mí,

Kin ní ọ̀hún wù mí,

Ó buyì koòṣà.

Ká fárí apákan dá apákan sí,

Kin ní ọ̀hún wù mí,

Ó buyì nífẹ̀ Ọọ̀ni,

Ó buyì koòṣà.

Ìkúnlẹ̀ búrúbúrú

Kin ní ọ̀hún wù mí,

Ó buyì nífẹ̀ Ọọ̀ni,

Ó buyì koòṣà.

Obì ifin,

Obì ipa,

Kin ní ọ̀hún wù mí,

Ó buyì nífẹ̀ Ọọ̀ni,

Ó buyì koòṣà.

Oje ọwọ́ sẹ̀gisẹ̀gi,

Kin ní ọ̀hún wù mí,

Ó buyì nífẹ̀ Ọọ̀ni,

Ó buyì koòṣà.

Iyán funfun nẹnẹ

Kin ní ọ̀hún wù mí,

Ó buyì nífẹ̀ Ọọ̀ni,

Ó buyì koòṣà.

Aṣọ funfun nẹnẹ

Kin ní ọ̀hún wù mí,

Ó buyì nífẹ̀ Ọọ̀ni,

Ó buyì koòṣà.

Yéèpà òrìṣà

Kin ní ọ̀hún wù mí,

Ó buyì nífẹ̀ Ọọ̀ni,

Ó buyì koòṣà.

Ṣẹ́ṣẹ́ ẹfun 

Kin ní ọ̀hún wù mí,

Ó buyì nífẹ̀ Ọọ̀ni,

Ó buyì koòṣà.

Àgógó ẹnu, 

Orí tí kìí jeku,

Orí tí kìí jẹja,

Tí kìí jògòǹgó 

Àfomi ọbẹ̀ lóòrè.

Kin ní ọ̀hún wù mí,

Ó buyì nífẹ̀ Ọọ̀ni,

Ó buyì koòṣà.

Ṣebí mẹ́jọ làgbà ìjòyè tí ń bẹ lápá ọ̀tún.

Mẹ́jọ làgbà ìjòyè tí ń bẹ lápá òsì.

Àgbà ìjòyè di mẹ́rìndínlógún 

Tí í bólúfẹ̀ gbìmọ̀ràn.

Èmi kí wọn nífẹ̀ Oòdáyé,

Ibi ojúmọ́ tí í mọ́ wa



© Adémọ́lá Ọlámìídé E.


              ORÍKÌ ÌLÚ Ọ̀YỌ́



Ọ̀yọ́ ọmọ aláàfin.

Òjò pa ṣèkẹ̀rẹ̀ ma dẹ̀. Ọmọ Àtìbà.

Ọmọ ò-kólówó pé kó gbowó.

Ò-kọ́wọ̀fà pé kó fọfàá lẹ̀

À ṣé kó lè bá à dìjà.

À ṣé kó lè bá à daápọn ni.

Kọ́mọ́ ọba Ládéyẹrí lè rí n̄ǹkan sè jẹ.

Ọmọ ládé làdè ládé.

Aláàfin ò ládé

Adé aládìkún là á dì fáláàfin.

Ọ̀yọ́ ladé wà,

A ò kówó radé.

Ajíṣe-bí-ọ̀yọ́ là á rí.

Ọ̀yọ́ ò ní ṣe bí i baba ẹnì kọ́ọ̀kan.

Pínníṣín lọmọ erin ti ń jogún ọlá.  

Lerin ti ń fapá ọlá yagi.

Ọ̀yọ́ ló ni ká rìn ká ṣánpá.

Ọ̀yọ́ ló ni ká rìn kó yẹ̀ẹ̀yàn.

Mo yíkàá ọ̀tún,

Mo yí tòsì,

Mo yíka ìṣẹ̀ǹbáyé.

Mo forí balẹ̀ fáláàfin.

Arọ́ba fín lọba ń pa.

Mo forí balẹ̀ fúnkú bàbá yèyé.

Òjò-pa-ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀-ma-dẹ̀

Ọmọ Àtìbà.

Ọ̀yọ́ ló ni ká rìn ká máa ṣánpá.

Kékeré lalágẹmọ baba wọn ti ń pọlá níyan.

Wọ́n mọ Yoòbá sọ níwọ̀n.

Wọ́n mọ fìlà kórígẹ̀ sórí.

Níbi wọ́n ń pé kólówó ó gbowó,

Kóníwọ̀fà fìwọ̀fà lẹ̀.

À ṣé kó lè dogun,

Kó lè dìjà 

Kọ́ba le rí jẹ níbẹ̀ ni.

Ẹ gbọ́ kín ní ń jóòṣà níwájú ọba?

Èmi ní ń jéégún níwájúu kábíyèsí?

Ọ̀yọ́ lọmọ ikú,  

Tíkú ò gbọdọ̀ pa.

Ọ̀yọ́ lọmọ àrùn, 

Tárùn ò gbọdọ̀ ṣe

Ọ̀yọ́ lọmọ òfò, 

Tófò ò gbọdọ̀ ṣe.

Ọ̀kòtó kan ò gbọdọ̀ ṣe.

Ọmọ àkóbá ilé.

Ọmọ àdábá òde ni.

Ikú tí ń p'ọmọ, 

Tí baba ń dúpẹ́.

Àrùn tí ń ṣọmọ tíyàá ò gbọdọ̀ gbin ni.

Ọ̀yọ́ dákun má mà bá mi jà o.

N ò sí nínú ẹni tí ń bínú ọba.

Toráláàfin ò bímọ kó máa wọlá ọlọ́lá kiri.

Ọba Ọ̀yọ́ ò bíìyàn,

Kó lọ rè é singbà.

Àsìngbà lóun ó bòde Ọ̀yọ́ jẹ́.

Ajíṣe-bí-ọ̀yọ́ làá rí,

Ọ̀yọ́ ò ní ṣe bíi baba ẹnìkọ́ọ̀kan.



                       ©Rufai Suliat Ọmọlará



             ORÍKÌ ÌLÚ ÌBÀDÀN



Ìbàdàn mèsìọ̀gọ̀ 

Ọmọ ajòrosùn 

Ọmọ ajẹ̀gbín jẹ̀karahun 

Ọmọ afìkarahun fọ́rí mu

Ọmọ afi tọ́ọ́rọ́ yọ̀ ṣẹ̀sẹ̀

Ọmọ Ìbàdàn kúré

Mésìọ̀gọ̀ nílé Olúyọlé


Ìlú Ìbíkúnlé 

Alágbàlá jáyàjayà

Ìlú Àjàyí

ògbórí ẹfọ̀n ṣe fìlàfìlà

Ìlú Ògúnmọ́lá

Olódògbo kẹrìkẹrì

Ò wọ kẹ̀m̀bẹ̀ rebi ìjà

BÓlúbàdàn bá wọ ṣòkòtò péḿpé 

Ó mọ ọmọ baba ẹni tí í ṣe 

Ẹlẹ́yẹlẹ́ lomi tí tẹrú tọmọ ń pọn mu 

Aṣèjìrẹ̀ lomi àbùmu bùwẹ̀ nÍbàdàn

Ará pápá ló lomi kúdọ̀sà

Ará agodi ló lomi afúruru

Ara Ayẹyẹ ọ̀ kú lọ́dọ̀ kankan

Gẹ́gẹ́ lomi tí wọ́n ń pọn mu

Ààrẹ Ìbàdán lólodò Agbadagbùdù

Odò mẹ́ta laàgbọdọ̀ mu

Ọ̀kan lAkínyẹlé káyé yẹ gbogbo wa

Ọ̀kan lÒgùnpa

Ọ̀kan ni kúdẹtì

Ìbàdàn bẹ̀ẹ̀rẹ̀ kó o tóó wọ̀ ọ́

Ibi olè ń gbé jàre olóhun

Wọn á ní ' o ṣe gbé e bẹ'

Ìbàdàn gbonílé gbàlejò

Ìbàdàn májà májà 

Eni tóo bájà yóò tẹ́

Ọmọ Lágelú rọra bínú

Rọra bínú jógun ó simi 

Ọmọ agbeni níjà tí kìí bẹ̀rù ọ̀tẹ̀

Ẹni wá sÍbàdàn tí kò mọ̀

Ẹ sọfún-un pé lálúpọn lòpin Ìbàdàn

Ìlú Látóósa

Ààrẹ ọ̀nà kakaǹfò

A kìí wáyé kámá láárùn kan lára

Ìjà ìgboro làrùn Ìbàdàn

Ǹlẹ́ ọmọ Mèsì ọ̀gọ̀

Ọjọ́ a bá pé èégún èégún a jẹ́.

Ọjọ́ a bá pé orò lorò ń gbà.


© AbdulJelil Kabirat Olúwakẹ́mi


           ORÍKÌ ÌLÚ ÌBÀDÀN


Ọmọ ajẹ̀gbín-jẹ̀karaun.

Ọmọ afìkaraun fọ́ri mu.

Ìbàdàn mọjà-mọjà tó fi káráawájú lẹ́rú.

Ìbàdàn ìlú Òjó,

Ìlú Àjàyí,

Ìlú Ògúnmọ́lá olódògboo kèríkẹrì

Ọ̀-wọ-kẹ̀ǹbẹ̀-rebi-ìjà.

A kìí wáyé ka má lárùn kan.

Ìjà ìgboro làrùn Ìbàdàn.

Àgbàlá Ọ̀gúnmọ́lá ti tó ìkokò sáré

Ọmọ olúpinmọ̀ǹde sobónyọké

Eégún di méfà l'Èkó ilé. 

Emi ní ṣe tóbìnrin ò mawo?

Pàká ló di méfà nígbàlẹ̀.

Kín ní ṣe tóbìnrin ò mawo?

Ẹ̀wù di méfà mo lù ú gbógbógbó.

Ẹ wo aṣeégúngún bó ṣe lu ká mi lára bí ajere.

Tí wọn bá ń sọ pé Ìbàdàn tí ò pójúlówó,

Ẹ wí fún wọn pé baba ti wa ló mú baba ti wọn lẹ́rú lójú ogun.

Ọmọ agbẹ́gimọ́lẹ̀,

Tí ń bére jà.

Ọmọ agbẹ́gimọ́lẹ̀ tí ń bére jà nílé ará Olúyọ̀lé

Ẹ̀yìnkùlé nìgbàlẹ̀.

Ó tigbórò ṣẹ̀

Ó tìgbàlẹ̀ ṣẹ̀

Eégún tó bá tìgboro ṣẹ̀,

Aṣọ rẹ̀ á pọ́n.

Ẹ̀yí tó bá tìgbàlẹ̀ ṣẹ́.

Ajá kìí jaṣọ ẹ̀sà ọ̀gbìn.

Ọmọ Lágẹlú.

Ọmọ ọ̀rọ̀ àpáta-má-fidà

Tíi pa ọta sílẹ̀ kíjà ó tó dé.

Ẹni tá a bẹ̀ kó má jagun mọ́,

Tí tún ń léwọ́ ogun.

Ìbàdàn ọmọ ajòrosùn.

Ò fẹgbẹ ogun ńlá ṣagbára odi.

Ẹ̀yin náà ni ó múra ìjà bí ẹní mọ̀ tẹ́lẹ̀.

Ìlú tóyìí, kò nígbó nílé.

Ìlú tóbi tó èyí, wọn ò ní gbèdéke ọba

Ìbàdàn ọmọ ajòrosùn.

Ọwá ló nìlú Ìjèṣà,

Aláké ló nìlú Ẹ̀gbá.

Irú wá, ògìrì wá ni ó gbilẹ̀ nílùú Ìbàdàn.

Ìlú Olúyọ̀lé.

Ìlú ológun.

Ìlú Ògúnmọ́lá.

Ìlú Àjàyí.

Ìlú Ìbíkúnlé olókè agbàǹgbà.

Ìbàdàn lo mọ o ò mọ Lálúpọn.

Lálúpọn sì ni baba Ìbàdàn.

Àgbàlá Ọ̀gúnmọ́lá ju oko baba elòmíràn lọ.

Ọmọ aríké-yọ- gbọgán.

Òjò là á rómi wẹ̀ nílé Arólú.

Arólú owó.

Ará ògbojò,

Wọn ò kìí fọkọ́ kankan nígbàlẹ̀.

Bí ènìyàn bá fọkọ́ kankan nígbàlẹ̀,

Bó ṣá baba rẹ̀ lọ́kọ́,

Mo lémi ò ní fọkọ́ kan bàbáà mi.

Iwájú Ológbojò igba eégún ni.

Ẹ̀yin Ológbojò igba eégún ni.

Ọ̀tún Ológbojò igba eégún ni.

Òsì ológbojò igba eégún ni.

Mo wòkè, mo wòsàlẹ̀,

Èmi ò ríbi n ó kẹ́gbẹ́ eléégún sí mọ́

Ológbojò ṣọbọ́nyọké, ọmọ aríké lò.

Ọmọ arómi wẹ̀ nílé Arólú.



©Rufai Suliat Ọmọlará.



             ORÍKÌ ÌLÚ ÒṢOGBO


Òṣogbo òròkí ọmọ àsálà

Ọmọ ààrè ò pẹtà.

Ààrè pẹtà wọ́n gbà á ńlé yín níjọ́sí.

Lónìí èmi ríbà baba tó bíi yín,

Báàrè Tìmí bá pẹtà ẹ má gbà á lọ́wọ́ mi.

Aró ń bẹ lÓṣogbo loṣogbo ń wu ní lọ. 

Ọ̀ṣọ́ ń bẹ lÓṣogbo loṣogbo ń wu ní lọ. 

Àta Ọ́ja ń bẹ lÓṣogbo loṣogbo ń wu ní lọ. 

Odò Ọ̀ṣun Ọ̀ṣẹ̀ǹgẹ̀ṣẹ́ ń bẹ lÓṣogbo loṣogbo ń wu ní lọ. 

Òṣogbo òròkí ìlú aró...


         ©Ademola Olamide E. 



          ORÍKÌ ÌLÚ ÌLOÒBÚ


Ìloòbú àṣàkẹ́,

Ọmọ-a-rà-rán mọ́ rasọ.

Ọmọ àkítí-olú,

Ará tápà léǹpe nílé ọya.

Ìwọ ọmọ ẹja ń bẹ lódò ,ẹ kò batan.

Ọmọ kọ̀ǹkọ̀ ń bẹ lódò ẹ kò ba sọ̀rẹ́.

Àfi ọ̀pọ̀lọ́ ẹlẹ́gbàáàyi ni ẹrí bá tan.

Ọmọ ibú ojútù adi ara lẹ̀ dogun.

Ogun kò jàjà kí ó kó ìloòbú rí.

Bí ogun bá gba iwájú ogun á tẹ́, 

Bí ogun bá gba ẹ̀yìn ogun kò lè rọ́nà lọ.

Sèbí ibú-ojútù ni ó kó gbogbo ogun lọ.


                 ©Gbenga 




         ORÍKÌ ÌLÚ ÌKÒYÍ


Ẹ̀ṣọ́ ìkòyí

Ọmọ agbọ̀ọyùn.

Ọmọ ogun ń lé mi bọ̀ lẹyìn

Ọ̀dọ̀kun-ǹ-sọsọ-ǹ-sọsọ.

Ìkòyí ní kàkà k'óun kó sódò,

Òun ó sì máa bógun lọ.

Ọmọ àlè Ìkòyí ní ń fẹ̀yìn gbọfà.

Gban̄gbawájú ni bàbá wọn fi ń gbọta.

Níjọ́ ogun fẹ́ kó baba yín, 

Ẹyẹ ntà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló bá Oníkòyí dìde ogun.

Ó ní 'ìwọ ayékòótọ́ gbéra ńlẹ̀ o dìde'.

'Ẹ̀lúùlú gbéra ńlẹ̀ o dìde'

'Àparò gbéra ńlẹ̀ o dìde'.

Ǹlẹ́ ẹ̀ṣọ́ ìkòyí,

Ọmọ agbọ̀n tíi yáàrùn ọ̀tẹ̀.

Ọmọ gbọ́in, 

Ọmọ gbin.

Ọmọ gbọ̀in-gbọ̀in tíi dì mẹ́ṣin lẹyìn ẹsẹ̀ gbagba.

Kò jẹ́ kẹ́ṣin Oníkòyí ó rogun.


Obìnrin ìkòyí,

Wọn kìí pàgbọn níkòyí ilé.

Ọjọ́ tí wọn bá pàgbọn níkòyí ilé,

Etí ogun ni wọ́n máa ń rán bàbá wọn.

Ọmọ Oníkòyí kan ò gbọdọ̀ jòkété.

Àtúngún ni baba wọn fi ń ṣe.

Àṣẹ̀yìnwá-àṣèyìbọ̀ lọ́mọ bíbí Oníkòyí ti í fapá ewúsá jẹ̀kọ.

Ìkòyí mọ̀lọjà, igbọ́n nílé, erúá singi-singi.

Abé ìlusùn àrònì gùdùgùdù-mọjà.

Akọ eyín tí í jẹ òkúta.

Ìkòyí ẹ̀ṣọ́, ọmọ agbọ̀n tí í bèèrè ìjà.

Yánbínlólú, orígun méje ni wón ń gbà ṣígun níkòyí ilé.

Méjèèje ni mo mọ̀.

Alápásá, ogun ní ń lọ.

Ọlọ́bẹ-ìṣìlò, ogun ní ń lọ.

Onípínnípínní, ogun ní ń lọ.

Tálápó bá ṣáájú,

Ọlọ́fàa tẹ̀le,

Oníbárà làárín.

Alákàtàpó ni yóò ṣìkẹyìn ọmọ ogun.

Ìkòyí ẹ̀ṣọ́,

Ọmọ arẹ́rìn-ín rèé kukúlójú 

Ọmọ mo dúró níjọ́ ogún le.

Mo sùn kàkà, 

Mo gbáriwo ọ̀run rọ̀yìn-rọ̀yìn. 

Nílé ìkòyí, ọmọ agbọ̀n tí ò ríkú sá.


Ogun àjàwẹ́yìn ló  ń  múlé ẹ̀ṣọ́ wù mí.

Ògun ojoojumọ́ ló múlé igbọ́n sú mií lọ.

Ará ìgbọ̀nmọpo, ọmọ ìjà-ọsẹ̀.

Ọmọ singi-singi abẹ́ ìrosùn.

Ìkòyí ò rógun jà, ó yìnbọn jẹ.

Nílé ìkòyí, ọmọ agbọ̀n tíí yáàrùn ọ̀tẹ̀.

Ìkòyí lẹ mọ̀,

Ẹ ò mọ Gbórógodólú.

Ọmọ akúwọ́ran, ọmọ asùnwọ́nran.

Ọmọ àpàyàkàtà bá n dínà ọlọ̀tẹ̀.

Ìkòyí ẹ̀ṣọ́ ọmọ adìílẹ̀dogun.

Ọmọ gbélé, gbéjù, gbégbèé.

Ìkòyí ò mọ̀ pébìkan la kìí gbé mọ́.

Igbó nìkòyí ń gbé,

Wọn kìí gbégboro,

Nítorí kínni kan sì kọ́,

Nítorí ọdẹ ṣíṣe ni.

Ogun ajàwẹ̀yìn ló ti méṣọ wù mí.

Ogun ojoojumọ́ ló múlé igbọ́n ṣú mií lọ.

Ọmọ ogun ká mi mọ́núugbó,

Mo dolúugbó.

Ọmọ ogún ká mi mọ́nú ọ̀dàn,

Mo dolú ọ̀dàn

Ìkòyí ẹ̀ṣọ́, ọmọ Ajagun bíi akúra.

Ọmọ akúfẹ́yẹ mú je.

Ọmọ akútapó tọrun.

Ọmọ dùgbẹ̀ là ń rùkú aláìgbọnràn.



            © Rufai Suliat Ọmọlará



             ORÍKÌ ÌLÚ ÒǸDÓ


Ọmọ Òǹdó ẹ̀gìnì

Ọmọ a wórin túnrin rọ

Ejí- ní-gbé ará ìlágbẹ̀dẹ

Ọmọ a rẹ́yín jajá ògún

Jajá jajá Òǹdó sọ pé

Ẹyin ò ní jajá mọ́

Ọ̀ jàjá ni n óò máa pè yín bó dọ̀la.

 Òǹdó kan ò gbọ́dọ̀ jewé iná.

Wọn ò sì gbọ́dọ̀ wa ibẹ̀

Ejí - ní- gbé ni yín ará ìlágbẹ̀dẹ ọmọ a wórin túnrin rọ

Alágbẹ̀dẹ kan wọn kì í tẹ́wọ́ gbowó, wọn á ní gbé e dà sílè kí o máa lọ.

Ìrèmògún lo ti ń bọ̀ o ò bá mi mọ́kọ́ wá,

bí èmi náà bá lọ ṣàgbẹ̀dẹ n̄ ò ní bá ọ múṣu bọ̀ ó.

Ọmọ a rówó rówó

Ijọ́ Alágbẹ̀dẹ ò bá rówó tọlọ́kọ́ taládàá ni yóò máa róná mọ́ lọ́nà oko.

Ẹjí-ní-gbé ni yín ooo

Ejí-ni-gbé ni yín ooo

Ará ìlágbẹ̀dẹ

Ọmọ a wórin túnrin rọ oooooo


©Tósìn Ìyárẹ̀sì




       ORÍKÌ ÌLÚ MODÁKẸ́KẸ́


Modákẹ́kéẹ́,àkọ̀ráyè,

Ọmọ ògúntẹjúdò,

Ọmọ akin lójú ogun.

Omo ògúnsùwàpọ̀ ni Modákẹ́kẹ́ ilé.

Omo a tó fìjà gbò de.

Bí ìjà kò bá sí mọ́,

N̄ ó lọ te ìlú ìdákẹ́jẹ́jẹ́ dó;

Màá wá wo baba eni tí ó máa tó mí.

Ẹni tí ń mi kùkùté,

Ara rẹ̀ ni ń mì.

Ọmọ orórì i baba ẹni ni àá kú sí.

Ọmọ ẹyẹ àkọ̀ ò rí àràbà tí ń fohùn bí ènìyàn

Ní Modákẹ́kẹ́ ilé.

Ọmọ àkọ̀ má bá mi jà, n̄ kò ṣe ibi;

Ọmọ ẹni bá ṣe ibi ni ẹyẹ ń yọ lójú jẹ.

Ọmọ ẹyẹ gbè mí, n̄ kò ṣe ibi.

Ọmọ àkọ̀ gbà mí, n̄ kò dalè.

Ọmọ ẹni ẹyẹ bá gbè ní í lówó, Ọmọ ẹni àkọ̀ bá gbè níí dẹ̀ lọ́rùn ní Modákẹ́kẹ́ ilé.

Ọmọ afèdèjìnlẹ̀ bá ẹyẹ ìgbẹ́ sọ̀rọ̀.

Báà mèdè àkọ̀, 

Bí ọ̀bọ ni àárí.

Ẹ jẹ́ kí a kúkú kọrin tí ẹyẹ ní a máa kọ.

Ọmọ adákẹ́ jà bí èsù ọ̀dàrà.

Bẹ́ẹ̀ ni àkọ̀ráyè kò bẹ́nìkan ṣọ̀tá.

Ẹni tí ó bá tọ́ ẹyẹ ni ẹyẹ ń yọ lójú jẹ.

Ọmọ àkọ̀ráyè kò rójú ìrégbè.

Bí Modákẹ́kẹ́ bá ti jí, 

Ibi iṣé rẹ̀ ní ń lọ.

Ọmọ Ọ̀gbàgbà tí í gba ará àdúgbò.

Ó gba ará ilé,

Ó gba ará oko,

Ó gba èrò ònà tí ń lọ sájò.

Ọmọ òyígbiriyígbiri,

Ọmọ a bi òògùn yí gbìrìgbìrì lájà.

Ọmọ ọba lóde Ọ̀yọ́.

Ọmọ atéta kùnrin.

Ọmọ gbà mí, gbà mí, kò yẹ àgbà. 

Ọmọ gbà mí, gbà mí,kò yẹ ọmọ akin.

Omo a tó fìjà gbòde.

Omo mátànmí, n̄ kò tan araà mi.

Ọmọ eni tan ará rè ló d'àrìnnà kò...



© Olóyèédé Israel



       ORÍKÌ ÌLÚ ÌLỌRIN


Ẹnú-dùn-juyọ̀.

Ọmọ ẹgbìnrìn ọ̀tẹ̀

Ọmọ òpó kanran bíntín

Ọmọ òpó kanran bìntìn

Tíi bẹ lálède Ọ̀yun.

Òpó ò gbọ́ràn,

Wọ́n ní a kọjúu rẹ̀ síná.

Iná ò gbọràn,

Wọ́n ní á kọjúu rẹ̀ sómi.

Omi ò gbọràn,

Wọ́n ní á fi pọtí tó le.

Ọtí tó le wá ń kọ́?

Ẹ jẹ́ á fi fọ́mọ alágídí.


Ọmọ wo ni ò gbọràn?

Òun l'Àfọ̀njá.

Wọ́n kọjú ọmọ Mọ́ríléwá sógun.

Ogun náà ló jà jà jà tí ò padà wálé mọ́.

Ọmọ ẹnú-dùn-juyọ̀.

Ìlú tóbi tóyen,

Wọn ò léégún.

Kéú leégún wọn.

Akọ̀kọ̀ loròobẹ̀.

Ọmọ òpó róṣọ

Òpó gbọ̀já.

Yán-bí-n-lólú

Ọmọ alérí-ikú-pogun.

Ìlọrin Àfọ̀njá

Ẹnú-dùn-juyọ̀.

Ẹ̀yin lọmọ adìye yín ogún,

Adìye pogún.

Mọríléwá sọ pẹ́dìyẹ ò pọmọ rẹ.

Wọ́n gbẹ́dìyẹ tà, 

Wọ́n rawó


Awó yẹ́yin méjì,

Ó pàkan.

Kó tó pàkan ìyóókù,

Wọ́n tẹ́ pẹpẹ.

Wọ́n gbáwó tà,

Wọ́n rọ̀bọ.

Ọ̀bọ ń lósòó.

Wọ́n tún gbọ́bọ tà,

Wọ́n rajá.

Ṣe lajá tún ń jẹmí.

Wọ́n gbájá tà,

Wọ́n rọ̀yun.


Wọ́n rọ̀yun délé tán,

Wọ́n ní kỌ́yun ó wá gúnyán.

Ọ̀yun sọ pé òun ò mọyán gún.

Wọ́n ní kỌ́yun ó wá rokà, 

Ọ́yun sọ pé òun ò mọkàá rò.

Ọ̀rọ̀ ni baba yín sọ s'Ọ́yun níjọ́sí,

LỌ̀yun ṣe bínú lodò tó ń ṣàn.

Ta fi ń sọ pé,

Ará Ìlọrin,

 Èrò Ìlorin, 

Ọba ìlú Ìlọrin,

Ọmọ ìlú Ìlọrin,

Bẹ́ ẹ bá dÓyun, ẹ bù mu,

Bẹ́ ẹ dÓyun ẹ bùwẹ̀.

Torọ́yun bàbáa yín ló dodò nígbàgede.

Ìlọrin Àfọ̀njá, enú-dùn-juyọ̀.


©Rufai Suliat Ọmọlará



       



          ORÍKÌ ÌLÚ Ẹ̀GBÁ


Ẹ̀gbá ọmọ Líṣàbí Agbòǹgbò Àkàlà.

Ọmọ erín jogún ọlá

Ọmọ ò-ṣílèkùn-palẹ̀kùn-dé

Arídìí ògo lójú ogun

Bàbáa tèmi làá ròyìn ogun fágbẹ̀

Ọmọ eni dúdú ò sí nílé

Pupa tó wà nílé ò mọbẹ̀ẹ́ sè

Kò sóhun tí wọ́n ń ṣe ní Mẹ́kà táwa kìí ṣe l'Ẹ́gbàá tiwa

Wọ́n ń mumi sẹ́mí-sẹmì ní Mẹ́kà, 

Àwa ń mumi odò Ògùn l'Ẹ́gbàá wa.

Wọ́n ń gàràfá ní Mẹ́kà,

Àwa ń gòkè Olúmo l'Égbàá tiwa.

Ẹ̀gbá, ará Akémàjó,

Ọmọ Màjójó l'Ófà

Kùńkùndun ń jẹni

Ẹ̀yin lọmọ ajógbẹrú

Má jòó gbẹ̀kọ

Nítorí, erú ní ń sínni

Ẹ̀kọ kìí sìnnìyàn.

Ọmọ atẹ́ní wíjọ́-wíjọ́

Tí irun rẹ̀ má gbọ̀n-ọ́n lẹ̀ tẹrẹtẹ.

Onírúurú Ẹ̀gbá pọ̀ nílé Aláké,

Olúgbọ́njọbí lolórí wọn.

Ìjà kan ìjà kàn 

Tí wọ́n jà lọ́jà

N ló túlùú Ẹ̀gbá orílé

N ló sọ Ṣódẹkẹ di baba ogun lábẹ́ Olúmọ.

Ẹ̀gbá ọmọ òru là á ṣèkà.

Ẹní ṣerúu rẹ lọ́sàn-án ńkọ́?

Kò níí farare lọ

Nílé baba tó bí wa lọ́mọ

Ẹ̀gbá méjì kìí jara wọn níyàn.

Bọ́kan bá ń wí báyìí sí

Èkejì a sì ní báa

wà.

Onírúurú Ẹ̀gbá pọ̀ nílé Aláké.

Ẹ̀gbá Àgùrá

Ẹ̀gbá Òwu

Ẹ̀gbá Òkè-ọnà

Ẹ̀gbá Aláké.

Gbogbo wọn ni wọ́n gba Ìjàyè lálejò lábẹ́ Olúmọ.

Lọ́jọ́ kan ọ̀jọ́kán

Lọ́jọ́ kan ọ̀jọ̀kàn

Lọ́jọ́ iná ogun ń rú tutuutu.

Aké orí Ẹ̀gbá Ṣẹkẹwuru.

Olówó orí ẹyọ tòjò-tẹ̀rùn

Ẹ ǹ lẹ́ o

Ará Akémàjó

Màjó méjì

Ará ajógbẹrú

Má jọ̀ó gbẹ̀kọ

Ẹrú ní ń sínni,

Ẹ̀kọ kìí sìnnìyàn

Ẹ̀yin ni ọmọ agbojo lọ́wọ́ ogun 

Ẹ̀yin ni ọmọ agẹ̀ṣin bàǹbà

Agẹṣin bàǹbà

Egúngún tó roko 

Tó roko pẹ̀lúù mi 

Ẹ ní kó pẹ̀lúù mi.

Orí á máa gbóore kalẹ̀ lọ́jà

Tìlájẹ̀bi, tarọ́mọ ṣe

Àyọ̀ǹbọ̀rọ̀ nírẹ̀kú

Ọmọ Lákéésìn

Ẹ̀gbá ọmọ Líṣàbí Agbòǹgbò Àkàlà

Ọ̀sán là á sòótọ́.

Ọmọ ẹja tó ń gbénú ibú ṣoró

Ọmọ erèkú ṣàwọ̀ rọ̀mì-rọ̀mì.

Ẹ̀yin lọmọ atẹ́ní wíjọ́ wìjọ̀ wíjọ́

Kírun rẹ̀ ó má gbọ̀n-ọ́n lẹ̀ tẹrẹtẹ.

Ọmọ agúnnújugún

Egúnnugún pẹ̀lúù mi.

Ará Aké,

Ẹ jó l'Ótìí 

Kẹ́ ẹ ná lọ rè é jó l'Óbà

Ẹ̀gbá, aróoko Adágbá.

Ogun ló lé baba wọn dábẹ Olúmọ.

Ẹ̀gbá ọmọ Líṣàbí Agbòǹgbò Àkàlà

Ogun òun ọ̀tẹ̀ ló lé wọn kúrò lórílé.

Oko Adágbá ni wọ́n ń sùn níbẹ̀ lolú fi mọ.

Kò sógun mọ́,

Kò sótẹ̀ mọ́,

Olú to gbà yín là.

Ogun ò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ṣe eni ní wàhálà níjọ́sí.

Kólúwo tó dá wàhálà ọ̀hún dúró.

Ibi tí Olú gbé fi wàhálà wọn mọ ni ń j'Ólúmọ.

Oko Adágbá ni wọ́n sì fi ibùsọ sí.

Ni wọ́n ṣe gbára jọ pọ̀ níbẹ̀.

Égbá pọlá pọ,

Ẹ jọ dìlú ńlá.

Ọmọ Olúmọ, ọmọ abẹ̀lọrọ̀.

Mo ṣọmọ Aláké, 

Mo ṣẹ́nu wíyẹwíyẹ́.

Mo ṣ'Ẹ̀gbá mo ṣohùn dídùn.

Ọmọ abìpàkọ́ ayánrògbolẹ̀ súké-súké

Ọmọ Ẹ̀gbá ìbà gbogbo.

Ọmọ aké orí Ẹ̀gbá Ṣẹkẹwuru.

Olówó orí ẹyẹvàbá tòjò-tẹ̀rūn

Gbogbo ọmọ Ẹ̀gbá lọmọ ọ̀-ṣílẹ̀kùn-palẹ̀kùn-dé.

Bó ṣelé, bó ṣòde,

Ẹ̀yin lọmọ akiti-káká

 A-jí-tówọ́-àlejò-bọnu.

Ẹ̀gbá gbalé,

Ẹ̀gbá gboko.

Ìgbàkúùgbà lẹjọ́ Ẹ̀gbá ń jàre.

A bímọ láké fọlá jagun.

Ẹ̀gbá fọlá jà, ó fèpè jà.

Ọmọ Ẹ̀gbá onígbẹ̀du àlùlà.

Ẹ̀gbá onígbẹ̀du à-lù-lówó-lọ́wọ́.

Alágogo ọ̀rànńyàn tan-tan-tan.

A bíni láké.

Mo ṣẹnu gbígbóná bíi jeje.

Wọ́n bí mi lẹ́gbàá mo gbó lóhùn bí ọ̀jẹ̀.

Ẹ̀gbá lẹ̀gbàá ń jẹ́ ní gbogbo ilẹ̀kílẹ̀.



©Rufai Suliat Ọmọlará


              ILU ÈJÌGBÒ


Ọmọ Ewú ìwínrín

Adálẹ̀ gbin isú kọ

Adálẹ̀ gbin Ewùrà

Ọmọ Adálẹ̀ gbin isú ìgángán

Ọmọ Ewú filé hàn mí

Ewú fọ̀nà hàn mí

Ewú kò ní fi àbùjá han ilé ìkirè

A kìí gba ojú ilé wọ ilé ìkirè

A kìí gba ẹ̀kùlé wọlé ìkirè

Emu

Ẹni bá gba ojú ilé wọlé ìkirè

Yóò san igba obì

Ẹni gba ẹ̀yìkùlé wọlé ìkirè

Yóò san igba atare 

Ewú ló bí mi

Mi ò gbọdọ̀ mẹmu

Ògìyán ló wò mí dàgbà

Mi ò gbọdọ̀ mu ògbùrọ́

Èyí tí mo gbọ́dọ̀ mú ò sí

Mọlúfọ́n adé ni yín

Èrèlú akẹ̀láwẹ̀

Ọmọ mo níyọ̀ nílé

Mo jẹ àtẹ́

Mo lé po nílé

Mo jẹ ilá ní funfun

Mo ní ẹní nílé

Mo sùn lẹ́ẹ̀kan

Mo rìn hòhò lọjà láàjìn

Ẹni pè yín láàjẹ́ kò purọ́

Egun Akuké lẹ fi ń tẹ̀pá òsoro jáko

Ẹ̀jẹ̀ ènìyàn lẹ fi ń kosù láàjìn

Èrèlú niyí nílé àwọn baba ẹ̀yin

Ọmọ olórìsà ń lá àjọbọ

Ọmọ agúnyán funfun

Ọbẹ̀ funfun

Aṣọ funfun

Fún òòsà funfun..




               Ademola Olamide E.



ÌLÚ YÀKÓOYÓ 


Yàkóoyó òòò

Yà kóo wáà yó èrò ọ̀nà

Ọmọ Ajibéwé ọmọ olúlàmókùn

Ọmọ ọlọ́jà tó tẹ̀lú dó

Ọmọ ògbójú olójà tó rójòyè Ọba láṣọ

Ọmọ agbelélé ṣe bí ẹbọra

Ọmọ afi nǹkan wínníwínní bora sùn

Ọmọ ọ̀rúnlàmókùn asẹ̀rọ̀

Ọmọ asẹ́ tí í mumi kíkan

Ọmọ amùgì tútù láìrò

Ọmọ olórò

Ọmọ Àlúkú

Ọmọ agbórí ọparun rétereté

Yúnmu yúnmu lorò ń ké

Báa bá gúnyán fàlúkú

Orò a kùn yùnmù yùnmù

Báa rokà fàlúkú

Orò a kùn yùnmù yùnmù

Àlúkú lẹ́ko tòle tòle lòun ó jẹ, lòun ó jẹ

Ògì tó kàn tó kàn lòun ó mu, lòun ó mu

Ọmọ èpè já joògùn

Ọmọ apèsè sílè dọmọ àlejò

Ọmọ yínmi yínmi gbìn kìn

Ọmọ igi pẹlẹbẹ tíì fira rẹ̀ ní nàkàn-nàkàn

A gbékòkò ó dolú igbó

A gbékòkò délé ó diwin àkúnlẹ̀bọ

A gbékòkò délé ó dolódùmarè

Yàkóoyó ómo adáko bìrì sowo

Yàkóowáàyò

Yà kóo wàá yó èrò ọ̀nà

Ẹni tí kò yà kóyó ebi níí lu irú wọn pa

Ọmọ òpómúléró mọjà àlekàn

Yúngbà yúngbà lorò ń dùn ní ìwárọ̀

Ọmọ Àlúkú ilé Ẹ̀gbá

Ọmọ asẹ́ tíì mumi kíkan


Ìfẹ́olúwa Elizabeth Ìdòwú


Olóòtú 

Adémọ́lá Ọlámìídé E.

Comments

Post a Comment

Popular Posts