Ẹ̀RỌ̀

Kó bá ti dára tó kí ìgbà yìí má wáyé rárá.
Ṣé ǹ bá mọyì, bóyá ni máa moore?
Ìgbà ọ̀dá nìgbà yí,
Ìgbà ooru ni.
Fínáfíná jọ̀wọ́ dẹ̀ ẹ́ 
Jẹ́ á rímú mi.
Òǹrò rọra má jẹ̀ ó dànù.
Ó kú dájú pé bó pẹ́ títí yóò yi.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ikun ọ̀tún tilè ti bọ́ sí tòsì .
Kí tòsì ti bọ́ sí tọ̀tún. 
Bígbẹ́yìn yóò bá dùn,
Bó bá jẹ́ lóòótọ́ adùn ni yóò gbẹ̀yìn ewúro;
A ò bá rọ́jú
Ká forí tì í
Ká fọrùn rọ́ ọ.
Ilá tó níforítì kìí kó
Ikàn tó níforítì kìí wẹ̀wù ẹ̀jẹ̀.
Ẹyin tó níforítì níí dàkùkọ
Bá à níforítì, ó dájú pé,
A ó la àkókò yìí já
Ìgbà kan ò kúkú lọ bí òréré
Ayé ò tọ́ lọ bí ọ̀pá ìbọn ìgbà ẹ̀dá ò tọ́ lọ bí òṣùmàrè
Ẹ̀ jẹ́ á máa rọ́jú
Ẹ jẹ́ á máa rọ́nú pẹ̀lú
Bó kú ṣe ń rẹ ará ayé 
Náà ní ń rẹ ará ọ̀run.
Awọ ìlù yìí ti ró pọnlá tó
Yóò tó ya
Ìgbà tó yi
Tó ń dóòyì koni
Ìgbà yóò tó yí
Tẹ́kọ tó sàn yóò yi
Ẹ̀bẹ̀ mi rèé sí ọba òkè
Kó má jẹ̀ ó pẹ́, 
Kádúrósinsin má ti padà sẹ́yìn.
©SAINTPRADOL

Comments

  1. This is just too good and creating a feeling of hope for mankind..... KUDOS sir

    ReplyDelete

Post a Comment

Popular Posts