AJOGUN
a. ORÍKÌ IKÚ
Ikú abara dúdú họhọ
Ikú òrìṣà
Ikú ìránṣẹ́ olódùmarè
Ikú kò mọ ọmọdé
Ikú kò mọ àgbà
Afàríwísí pani
Ikú òrìṣà
b. ORÍKÌ ÈSE
Àbíkẹ̀yìn wọn léńje léńje
Kékere tíí págbà rán níṣẹ́
Ìmùlẹ̀ àwọn ìyàmi
Èse níí bíkú
Èse níí báàrùn
Èse níí bẹ́gbà
Akọ ajá aborí gbongbo
Èse abìrù gìlọ̀
Èse má ṣe mí
N ò ní ṣìṣe.
d. ORÍKÌ Ẹ̀GBÀ
Ẹ̀gbà níí gba tọwọ́ ọmọdé
Ẹ̀gbà níí gba tọwọ́ àgbà
Ẹ̀gbà má gbare mi dànù
Aṣọni dí oníǹkan àná
Ẹ̀gbà má gbare mi dànù
A sọlọ́mọ di àgàn alẹ́
Ẹ̀gbà má gbare mi dànù
Ẹ̀gbà délé òrí ó kọjú rẹ̀ sóòrùn
Ẹ̀gbà má gbare mi dànù
Ẹ̀gbà délé kànún wọ́n dá kánún sómi.
Ẹ̀gbà má gbare mi dànù
Ẹ̀gbà délé iyọ̀ ó yí i mérùpẹ̀
Ẹ̀gbà má gbare mi dànù
e. ORÍKÌ ÌYÀMI
Ìyàmi òṣòròǹgà
Apanimáwàágún olókìkí òru
Abapága abẹ́sẹ̀ga
Abìrìn-ẹsẹ̀-méjèèjì gà gà gà
Atorí japá
Atìfúnjẹ̀dọ̀
Atìfun-jòróǹro ọ̀gàlàta
Ẹyẹ abapá gẹẹ
Ẹyẹ abẹsẹ̀ gẹẹ
Ẹyẹ abìyẹ́-bàgẹ̀bàgẹ̀
Ẹ̀yin lòfúnni-ládìẹ-sìn-gbodidi-ẹran-lọ́wọ́-ẹni
Arógba-aṣọ-má-balẹ̀
Ọlọ́jàá ikú
Ọlọ́jàá àrùn
Ọlọ́jàá èse
Ẹ̀yin lakọ ajá aborí-póńpó
Èse abìrùgìlọ̀
Ọlọ́jàá àsápè
Ọlọ́jàá owó
Ọlọ́jàá ọmọ
Ọlọ́jàá àwòyè
Dúdú biribiri lọ́sàn
Funfun lóru
Ẹ̀yin ni ìyà mi ọ̀ṣàlàṣolo
Ẹ̀yin ni ìyà mi òṣòlòṣala
Ẹ̀yin lafínjú àdàbà tí ń jẹ láàárín òrófó.
Afínjú ẹyẹ tí ń jẹ ní gban̄gba oko.


Comments
Post a Comment