ORÍKĪ ẸYẸ
ORÍKÌ ẸYẸ
By Ademola Olamide E.
a. ẸYẸ KANNAKÁNNÁ
Kannakánná ṣojú rogodo gbé ẹyin
Kannakánná ẹyẹ àlúpàyídà
Kannakánná kan kì í yé
Ẹyin ẹlẹ́yin ni wọ́n sàba pa di tiwon
Ẹyin ẹyẹ tó bá sàba lé
Ọmọ tirẹ̀ ní í fi í pa
Dúdú mini bí ààjin òkùnkùn
Dúdú mini bí aró
Oníyẹ̀ẹ́ bàgẹ̀bàgẹ̀
Àjẹ́ ẹyẹ tí ń kú tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀.
b. ẸYẸ IGÚNNUGÚN
Igúnnugún ẹyẹ orí àko
Abàmí ẹyẹ tó ráyé
Abàmí ẹyẹ tó rọ́run
Abàmí ẹyẹ tí ń jòkú
Ẹyẹ aborí pa
Ẹyẹ abọrùn pa
Ẹyẹ àbìrìn ẹsẹ méjèèjì gàjàgàjà
Ìgún ẹyẹ ayé
Igún ẹyẹ àwọn àgbà
Ẹyẹ ìbẹ̀rú tí ń jẹbọ
Ẹyẹ ìbẹ̀rú tí ń jòkú ènìyàn
Bígún bá balẹ̀ á jẹ̀fun akọni.
Ìgún ẹyẹ ayé
Níkọ̀lé ilé
Igún wọlé
Igún gbá kuuru ṣẹbọ
Igúnnugún ẹyẹ ìwọ̀n loore
Igúnnugún ṣoore
Ó pá lórí
d. ẸYẸ Ọ̀KÍN
Ọ̀kín dé ọba ẹyẹ
Ẹ wá ilé kí ẹ̀ fọ̀kín sí
Pírí ayaba olójú oge
Ẹlẹ́sẹ̀ ẹwà
Aláṣọ ẹyàwáwòran
Oníyẹ̀ẹ́ àrà
Dára tán tí ń bọ́ba gbáàfin
Adé orí ọ̀kín
Kò jọ tẹyẹkẹ́yẹ̀
Oníyẹ́ gbàràdá.
e. ẸYẸ ÀKÀLÀMỌ̀NGBÒ
Ẹyẹ́ ńlá abìyẹ́ gẹ́gẹ́
Ẹyẹ ìbẹ̀rú atojú mẹ́ran jẹ
Gbáganlójú-mòòkùn ilẹ̀
Àkàlà ẹyẹ ọrùn oṣè
Àkàlàmọ̀ngbò ẹ̀yẹ̀ ayé
Àkàlàmọ̀ngbò ẹ̀yẹ̀ àgbà.
ẹ. ẸYẸ ATÍÁLÁ
Àgógó ẹnu kángunkàngun ọ̀ṣọ́ọ́rọ́kannú
Ẹyẹ abori so
Abẹ̀dọ̀-mejì-nikùn bi a jìfà
Olópòó ìrù tééré
Àgógó ẹnu atíálá tẹ́rù ni ò fi lè gberin ẹyẹ
Ti ẹ̀ tó o lẹ́rù ni ò fi lè fẹ̀sì ẹyẹ ẹ̀gà.
Atíálá abọ̀fun gbọ̀lọ̀tù
Atíálá ẹyẹ ajíjẹ̀-lórí-igi
Abẹ̀dọ̀ pòpòpò
Àgógó ẹnu mi tó mi rù ni kò jẹ́ n bá wọn wí jọ́
Ení wí tí ò dákẹ́ fẹnu pekú sórí ara rẹ̀.
f. ẸYẸ ORÒRẸ́
Oròré eye ọlọ́gbọ́n
Ta ló sọ pó ò lọ́gbọ́n
Òròré ò le jà?
Bí Öròré ò le jà
Ó mule tagbọ́n
Ẹyẹ a bágbọ́n ṣe
Ọgbọ́n inú ẹyẹ ò lè pẹyẹ
g. ẸYẸ LÉKELÉKE
Ma bẹ́lẹ́fun rẹ́ fún làwọ̀.
Àlà laṣọ ọba ẹyé dìmùlẹ̀ àdàbà.
Bágbe ti ń rẹra rẹ̀ láró
Tálùkò ti ń rẹra rẹ̀ lósùn
Ni lékeléke ti ń rẹra rẹ̀ lẹ́fun kẹnẹnẹ.
Àdàbà bà láràbà dàpéwò
Ẹyẹ asùwà rìn.
Ẹyẹko abọ́wọ̀ọ́ rín
Ko le jẹ níbi wọ́n gbé ń jẹ ti wọn.
A bẹsẹ̀ gínní
A bara funfun nini
Ibi agbo ẹrán ń rè lọ́dàn
A ti dawo àjọrìn
h. Adìyẹ
Adìyẹ òkòkòó
Ta ló sọ pádìyẹ ò pọmọre
Wọ́n gbẹ́dìyẹ tà
Wọ́n fowó rawó
Awó yẹ́n méjì ó pà kan
Bẹ́ẹ̀ sì ni adìyẹ a tọmọ ṣùùrù lẹ́yìn
Alágòógó tí ń dẹ́rù bàṣá
Òròmọdìẹ ò màwòdì
Ìyá rẹ̀ ló màṣá
i. PẸ́PẸ́YẸ́
Pẹ́pẹ́yẹ ẹyẹ lọmọ
Pẹ́pẹ́yẹ ò ní lọjà
Pẹ́pẹ́yẹ kìí kúkú odò
Ìran wọn a ti máa fomi ilé ṣeré
j. ORÍKÌ ẸYẸLÉ
Ẹyẹlé ò ní bónílé jẹ
Kó bónílé mu
Kó dọjọ́ ikú kó yẹrí
Ẹyẹlé ẹyẹ ẹnì
Ẹsọ̀ pẹ̀lẹ́ ẹyẹ ọ̀gbẹ̀jẹ̀
k. ÀDÁN
Kò ṣeku kò ṣẹyẹ
Tọ́ọ́rọ́ lọ́rùn igi
Àdán doríkodò
Àdán ń wòṣe ẹyẹ
Ẹyẹ tí yóò doríkodò bí àdán ò sí
Èyí tọ bá doríkòdò bí àdán
Tojú timú tènu rẹ̀ yóò ṣẹ̀jẹ̀
Àtọ̀lẹ̀dọ́lẹ̀ ni tàdán
Ẹyẹ atẹnu yàgbẹ́.
2024


Comments
Post a Comment