Ìṣòro tí ìmọ̀ èdè Yorùbá ń kojú

 Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní "àìfinúkonú àìfèròmerò ló mú ọmọ ìyá mẹ́fà kú sóko ìwọ̀fà mẹ́fà" . Ọ̀rọ̀ ìrònú àwa ọmọ Yorùbá kúrò ní èyí tí a lè ló dá ẹnì kẹ́ni sí tà bí kò kan ẹnì kàn. Ọ̀run ń yà bọ̀ ni, bí yóò ti kan ará ilé náà ni yóò kan ará oko.

Gbogbo ọmọ Yorùbá ló kàn yálà àwọn tí ó wà ní ìtẹdó ilẹ̀ Yorùbá, ìlú mìíràn àti ní òkè òkun. Kí a tó wà pẹ̀kẹ́ ku àkòrí yìí ní sàn-án, ó tọ́ kí a yànnànà àwọn òkùte ọ̀rọ̀ tí ó se gbòógì nínú rẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ náà ni Yorùbá, àṣà, ìmọ̀ ẹ̀dá-èdè, ọ̀làjú àti ohun àjogúnbá.

Àwọn wo gan-an ni a lè pè ní Yorùbá? Láìdéènà pẹnu, àwọn Yorùbá ni àwọn tí ọ̀pọ̀ wọn gbàgbọ́ pé Ilé-Ifẹ̀ ni wọ́n ti ṣẹ̀ wá, wøn rí Odùduwà gẹ́gẹ́ bí babańlá wọn; wọ́n sì ń ṣàmúlò èdè Yorùbá gẹ́gẹ́ bí  èdè àbínibí wọn.

Àṣà ni a lè pé ní ìgbé ayé àwùjọ́ ọmọnìyàn kan tí ó yà wọ́n sọ́tọ̀ láàrin àwùjọ mìíràn. Òhun ni a lè pè ní díńgí tàbí iná-àtẹ̀tàn tí a fi ń wò ìgbésí ayé àwùjọ ọmọnìyàn. Àṣà máa ń yípadà, nítorí ìhà tí irúfẹ́ àwọn ẹ̀dá tí a mọ̀ mọ àṣà yìí bá kọ sí i.

Ìmọ̀ ẹ̀dá-èdè nì èka ìmọ̀ tí ó dá lé bí a ti ń fi ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣàtúpalẹ̀ èdè. Nínú ẹ̀kọ́ yìí ni a ti ń wo àwọ̀n fọ́nrán ìhun èdè, ìtumọ̀ àti ìbáṣepọ̀ tí ó wà láàrin èdè àti àwọn ẹ̀yà ẹ̀kọ́ mìíràn láwùjọ ènìyàn.

Ọ̀làjú ni a lè pè ní ìdàgbàsóké tí ó dé bá àwùjọ tí ó mú kí ìyàtọ̀ bá ìgbésí ayé wọn tàtẹ̀yìnwá. Àjogúnba ni ohun tàbí ìṣe tí a jogún láti ìran kan dé òmíràn.

Comments

Popular Posts